Sefaniah Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ohun tí òǹkọ̀wé yìí ní lọ́kàn láti ṣe ni láti kéde ìkùsídẹ̀dẹ̀ ìdájọ́ Ọlọ́run lórí àwọn Juda. Ìparun tí Sefaniah sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ wá láti ọwọ́ àwọn Babeli lẹ́yìn tí wọn ti fún àwọn Asiria lágbára àti tí wọ́n ti mú agbára ìpìlẹ̀ wá sí òpin.
Kókó pàtàkì tí Sefaniah ṣàlàyé nínú ìwé rẹ̀ ni ìpadàbọ̀ Olúwa, nígbà tí Ọlọ́run yóò fi ìyà jẹ àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ṣe ìfẹ́ rẹ̀ gidigidi, papọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìmọ̀kan Juda. Ṣùgbọ́n Sefaniah tún jẹ́ kí ó di mí mọ̀ pé Ọlọ́run yóò fi àánú hàn sí àwọn ènìyàn rẹ̀ síbẹ̀: gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn wòlíì mìíràn, ó parí àwọn ìkéde ìparun rẹ̀, ó sì yí i sí rere pé Ọlọ́run yóò mú Juda dúró.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Àlàyé ìbẹ̀rẹ̀ 1.1-3.
ii. Ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ lórí Juda àti àwọn orílẹ̀-èdè 1.4-18.
iii. Ìdájọ́ Ọlọ́run lórí àwọn orílẹ̀-èdè 2.1–3.8.
iv. Ìràpadà àwọn ènìyàn tókù 3.9-20.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Sefaniah Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀