Titu Ìfáárà

Ìfáárà
Paulu kọ lẹ́tà yìí sí àwọn alábáṣiṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ tó fi sílẹ̀ ní erékùṣù Krete, láti ran àwọn ìjọ Ọlọ́run lọ́wọ́ àti láti mú ìjọ Ọlọ́run lágbára sí i. Iṣẹ́ Titu ni láti yan àwọn alàgbà àti láti fi ìlànà ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi. Ó pọn dandan fún Paulu láti lọ sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí àwọn tó ń di ipò alàgbà mú gbọdọ̀ ní, àti láti fún ìjọ Ọlọ́run ní ìmọ̀ràn. Nínú ìmọ̀ràn wọ̀nyí, Paulu fi ẹnu ba àwọn ìṣòro tó dojúkọ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti bí wọn yóò ṣe máa bá àwọn ìṣòro náà pàdé.
Nínú lẹ́tà rẹ̀, Paulu tẹpẹlẹ mọ́ ọ̀nà tí ó rọrùn tí Kristiani fi le gbé nínú ayé tí àyíká rẹ̀ kún fún ìkórìíra àti ìríra. Kí wọn sì le fihàn nínú ìgbé ayé wọn ohun tí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run jẹ́. Kí ìgbé ayé wọn sì jẹ́ àwòkọ́ṣe ju ọ̀rọ̀ ẹnu lásán lọ.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìkíni 1.1-4.
ii. Nípa yíyan àwọn alàgbà 1.5-16.
iii. Àwọn àkíyèsí fún àwọn ọmọ ìjọ Ọlọ́run 2.1-15.
iv. Ọ̀rọ̀ ìyànjú lórí ìgbé ayé Kristiani 3.1-15.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Titu Ìfáárà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀