Orin Solomoni Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìwé yìí ń ṣàlàyé ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ Israẹli bí wọ́n ṣe ń gbilẹ̀ sí i ní ọrọ̀. Nínú orin yìí, ìfẹ́ ni ó wá ọrọ̀ rí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọrọ̀ ló júwe ara rẹ̀ bí ọ̀kan nínú ẹ̀bùn tí Ọlọ́run yàn. Ohùn ìfẹ́ wà nínú orin bí ọgbọ́n ṣe wà nínú òwe. Ohùn obìnrin a máa polongo ìfẹ́, a máa sọ nípa ti ẹwà rẹ̀ àti bí ó ṣe ní iye lórí tó, gẹ́gẹ́ bi àpẹẹrẹ “Olùfẹ́ mi ni tèmi, èmi sì ni tirẹ̀,” (2.16). Ó jẹ́ kí ó yé ni pé ìfẹ́ ju agbárakágbára lọ, kò sí bí ọrọ̀ ènìyàn ṣe pọ̀ tó kò lè rà á bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀, nítorí pé ó jẹ ẹ̀bùn Olúwa fún ènìyàn.
Kò sí ẹni tí yóò ka ìwé yìí dáradára tí ó lè béèrè bí ó ṣe lo ọgbọ́n àtinúdá rẹ̀. Ó jẹ́ kí a mọ adùn tí ó wà nínú olùfẹ́ tí ọkàn ènìyàn fẹ́. Ìdí nìyí tí ó fi wí pé, “Olùfẹ́ mi ni tèmi, èmi sì ni tirẹ̀, ó ń jẹ láàrín àwọn ewéko dáradára” (2.16). Dájúdájú gbogbo wọn gbà pé ohun tó jẹ́ kókó nínú ìwé yìí ni ó wà ní (Orí Kẹjọ 8.6-7), ibi tí a ti rí agbára àti ìwúlò ìfẹ́, ìfẹ́ tó so ọkùnrin àti obìnrin pọ̀, ó sì tún dábàá pé kí ìfẹ́ máa tẹ̀síwájú.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Àkọlé 1.1.
ii. Ọkọ ń retí olùfẹ́ rẹ̀; Ìpàdé àkọ́kọ́ 1.2–2.7.
iii. Ìyìn obìnrin rẹ̀ ní ọ̀sán; Ìpàdé kejì 2.8–3.5.
iv. Ọkọ ìyàwó dé; Ìpàdé Kẹta 3.6–5.1.
v. Àlá rẹ̀ da ọkàn rẹ̀ láàmú; Ìpàdé Kẹrin 5.2–6.3.
vi. Èrò àtọkànwá tí ọkọ ìyàwó rò nípa olùfẹ́ rẹ̀; Ìpàdé Karùn-ún 6.4–8.4.
vii. Ẹwà ìfẹ́ 8.5-7.
viii. Ìkádìí 8.8-14.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Orin Solomoni Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀