Romu 12:3-16

Romu 12:3-16 YCB

Ǹjẹ́ mo wí fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wà nínú yín, nípa oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n kí ó le rò níwọ́ntún-wọ́nsì, bí Ọlọ́run ti fi ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún olúkúlùkù. Nítorí gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ẹ̀yà púpọ̀ nínú ara kan, tí gbogbo ẹ̀yà kò sì ní iṣẹ́ kan náà: Bẹ́ẹ̀ ni àwa, tí a jẹ́ púpọ̀, a jẹ́ ara kan nínú Kristi, àti olúkúlùkù ẹ̀yà ara ọmọnìkejì rẹ̀. Ǹjẹ́ bí àwa sì ti ń rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn gbà gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún wa, bí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, kí a máa sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìgbàgbọ́; Tàbí iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí a kọjú sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa tàbí ẹni tí ń kọ́ni, kí ó kọjú sí kíkọ́. Tàbí ẹni tí ó ń gbani níyànjú, sí ìgbìyànjú; ẹni tí ń fi fún ni kí ó máa fi inú kan ṣe é; ẹni tí ń ṣe olórí, kí ó máa ṣe é ní ojú méjèèjì; ẹni tí ń ṣàánú, kí ó máa fi inú dídùn ṣe é. Kí ìfẹ́ kí ó wà ní àìṣẹ̀tàn. Ẹ máa takété sí ohun tí í ṣe búburú; ẹ fi ara mọ́ ohun tí í ṣe rere. Ní ti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín; ní ti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣáájú. Ní ti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ; ẹ máa ní ìgbóná ọkàn; ẹ máa sìn Olúwa. Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí; ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú; ẹ máa dúró gbọingbọin nínú àdúrà. Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́; ẹ fi ara yín fún àlejò ṣíṣe. Ẹ máa súre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; ẹ máa súre, ẹ má sì ṣépè. Àwọn tí ń yọ̀, ẹ máa bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sọkún, ẹ máa bá wọn sọkún. Ẹ máa wà ní inú kan náà sí ara yín. Ẹ má ṣe gbéraga, ṣùgbọ́n ẹ má tẹ̀lé àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín.

Àwọn àwòrán ẹsẹ fún Romu 12:3-16

Romu 12:3-16 - Ǹjẹ́ mo wí fún olúkúlùkù ènìyàn tí ó wà nínú yín, nípa oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún mi, kí ó má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n kí ó le rò níwọ́ntún-wọ́nsì, bí Ọlọ́run ti fi ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún olúkúlùkù. Nítorí gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ẹ̀yà púpọ̀ nínú ara kan, tí gbogbo ẹ̀yà kò sì ní iṣẹ́ kan náà: Bẹ́ẹ̀ ni àwa, tí a jẹ́ púpọ̀, a jẹ́ ara kan nínú Kristi, àti olúkúlùkù ẹ̀yà ara ọmọnìkejì rẹ̀. Ǹjẹ́ bí àwa sì ti ń rí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹ̀bùn gbà gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí a fi fún wa, bí ó ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ni, kí a máa sọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ìgbàgbọ́; Tàbí iṣẹ́ ìránṣẹ́, kí a kọjú sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa tàbí ẹni tí ń kọ́ni, kí ó kọjú sí kíkọ́. Tàbí ẹni tí ó ń gbani níyànjú, sí ìgbìyànjú; ẹni tí ń fi fún ni kí ó máa fi inú kan ṣe é; ẹni tí ń ṣe olórí, kí ó máa ṣe é ní ojú méjèèjì; ẹni tí ń ṣàánú, kí ó máa fi inú dídùn ṣe é.

Kí ìfẹ́ kí ó wà ní àìṣẹ̀tàn. Ẹ máa takété sí ohun tí í ṣe búburú; ẹ fi ara mọ́ ohun tí í ṣe rere. Ní ti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín; ní ti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣáájú. Ní ti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ; ẹ máa ní ìgbóná ọkàn; ẹ máa sìn Olúwa. Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí; ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú; ẹ máa dúró gbọingbọin nínú àdúrà. Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́; ẹ fi ara yín fún àlejò ṣíṣe.
Ẹ máa súre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; ẹ máa súre, ẹ má sì ṣépè. Àwọn tí ń yọ̀, ẹ máa bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sọkún, ẹ máa bá wọn sọkún. Ẹ máa wà ní inú kan náà sí ara yín. Ẹ má ṣe gbéraga, ṣùgbọ́n ẹ má tẹ̀lé àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín.