Èmi sì rí i nígbà tí Ọ̀dọ́-àgùntàn náà ṣí ọkàn nínú èdìdì wọ̀nyí, mo sì gbọ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ń wí bí sísán àrá pé, “Wá, wò ó!” Mo sì wò ó, kíyèsi i, ẹṣin funfun kan: ẹni tí ó sì jókòó lórí i rẹ̀ ní ọfà kan; a sì fi adé kan fún un: ó sì jáde lọ láti ìṣẹ́gun dé ìṣẹ́gun. Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kejì, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè wí pé, “Wá, wò ó!” Ẹṣin mìíràn tí ó pupa sì jáde: a sì fi agbára fún ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, láti gba àlàáfíà kúrò lórí ilẹ̀ ayé, àti pé kí wọn kí ó máa pa ara wọn: A sì fi idà ńlá kan lé e lọ́wọ́. Nígbà tí ó sì di èdìdì kẹta, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kẹta wí pé, “Wá wò ó”. Mo sì wò ó, sì kíyèsi i, ẹṣin dúdú kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ní ìwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn kan ní àárín àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nì ti ń wí pé, òṣùwọ̀n alikama kan fún owó idẹ kan, àti òṣùwọ̀n ọkà barle mẹ́ta fún owó idẹ kan, sì kíyèsi i, kí ó má sì ṣe pa òróró àti ọtí wáìnì lára.
Kà Ìfihàn 6
Feti si Ìfihàn 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Ìfihàn 6:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò