Saamu Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìwé Saamu jẹ́ ìwé orin, àdúrà pọ̀ nínú rẹ̀, ó sì kún fún ìyìn. Àkọsílẹ̀ ìwé yìí ni àwọn ọmọ Israẹli máa ń lò fún ìsìn wọn. Ìwé yìí sì tún tẹpẹlẹ mọ́ onírúurú àdúrà bí i àdúrà fún ààbò, ìyọ́nú, ìrànlọ́wọ́, ìwòsàn, ìdáǹdè, ìpèsè, ìdájọ́ òdodo àti ọ̀pọ̀ mìíràn. Ìwé Saamu sọ nípa òdodo, òtítọ́, títóbi, gíga, agbára Ọlọ́run. Ó jẹ́ ìwé tó ń kọ́ ni ní àdúrà gbígbà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Saamu sọ̀rọ̀ lórí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹ̀bẹ̀, síbẹ̀ àdúrà ló ṣe pàtàkì jù nínú rẹ̀.
Dafidi nínú ìwé yìí yan àdúrà àti ìyìn láàyò púpọ̀. Ó máa ń bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nínú àdúrà àti nínú ìyìn pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti òtítọ́. Saamu ni ìwé tí ó pọ̀jù tí kò sì gbára le ohunkóhun, ó ní kókó tí ó yàtọ̀ sí ti ìwé tókù. Àwọn ohun tí ó túnṣe kókó nínú Saamu ni, ìgbé ayé ènìyàn tí ó kún fún òye, òtítọ́, ìrètí, ìsìn, ìwà rere àti ìgbéga, àti ìtàn dídá ayé. Bákan náà, Ọlọ́run sì tún fi títóbi agbára rẹ̀ hàn. Ó sì tún fi yé wa pé Ọlọ́run ni ọba tí ó tóbi jù. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó tún mẹ́nuba ìlérí Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn rẹ̀, ìlú Ọlọ́run àti tẹmpili tí Ọlọ́run ń gbé.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìwé kìn-ín-ní 1–41.
ii. Ìwé kejì 42–72.
iii. Ìwé kẹta 73–89.
iv. Ìwé kẹrin 90–106.
v. Ìwé karùn-ún 107–150.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Saamu Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀