Saamu 71:1-3

Saamu 71:1-3 YCB

Nínú rẹ, OLúWA, ni mo ní ààbò; Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí. Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ; dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí. Jẹ́ àpáta ààbò mi, níbi tí èmi lè máa lọ, pa àṣẹ láti gbà mí, nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.