Àwọn wo ni ó bẹ̀rù OLúWA? Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn. Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà, àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà. OLúWA fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀; ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn. Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ OLúWA, nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà. Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi; nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú. Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi; kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi. Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi, kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì. Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi, tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn. Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀; Má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú, nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi. Jẹ́ kí òtítọ́ inú àti ìdúró ṣinṣin kí ó pa mí mọ́; nítorí pé mo dúró tì ọ́. Ra Israẹli padà, Ìwọ Ọlọ́run, nínú gbogbo ìṣòro rẹ̀!
Kà Saamu 25
Feti si Saamu 25
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Saamu 25:12-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò