O. Daf 25:12-22

O. Daf 25:12-22 YBCV

Ọkunrin wo li o bẹ̀ru Oluwa? on ni yio kọ́ li ọ̀na ti yio yàn. Ọkàn rẹ̀ yio joko ninu ire, irú-ọmọ rẹ̀ yio si jogun aiye. Aṣiri Oluwa wà pẹlu awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀, yio si fi wọn mọ̀ majẹmu rẹ̀. Oju mi gbé soke si Oluwa lai; nitori ti yio fà ẹsẹ mi yọ kuro ninu àwọn na. Yipada si mi, ki o si ṣãnu fun mi; nitori ti mo di ofo, mo si di olupọnju. Iṣẹ́ aiya mi di pupọ: mu mi jade ninu ipọnju mi. Wò ipọnju mi ati irora mi; ki o si dari gbogbo ẹ̀ṣẹ mi jì mi. Wò awọn ọta mi, nwọn sá pọ̀; nwọn si korira mi ni irira ìka. Pa ọkàn mi mọ́, ki o si gbà mi: máṣe jẹ ki oju ki o tì mi; nitori mo gbẹkẹ̀ mi le ọ. Jẹ ki ìwa-titọ ati iduro-ṣinṣin ki o pa mi mọ́: nitoriti mo duro tì ọ. Rà Israeli pada, Ọlọrun, kuro ninu ìṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú O. Daf 25:12-22