Saamu 22:19-31

Saamu 22:19-31 YCB

Ṣùgbọ́n ìwọ, OLúWA, má ṣe jìnnà sí mi; Háà! Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wá fún àtìlẹ́yìn mi! Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà, àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá. Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún; Kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré. Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi; nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́. Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù OLúWA, ẹ yìn ín! Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un! Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli! Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra ìpọ́njú àwọn tí a ni lára; kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é. Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá; ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀ tálákà yóò jẹ yóò sì yó; àwọn tí n wá OLúWA yóò yin jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé! Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí wọn yóò sì yípadà sí OLúWA, àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀, Nítorí ìjọba ni ti OLúWA. Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè. Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn; gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀ àti ẹni tí kò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ ni ààyè. Irú-ọmọ rẹ̀ yóò sìn ín; a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ nípa OLúWA, Wọn yóò polongo òdodo rẹ̀ sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí, wí pé, òun ni ó ṣe èyí.