Saamu 19:1-10

Verse Images for Saamu 19:1-10

Saamu 19:1-10 - Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run;
Àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́;
wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.
Kò sí ohùn tàbí èdè
níbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn
Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayé,
ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé.
Ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.
Tí ó dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá rẹ̀ wá,
òun yọ bí alágbára ọkùnrin tí ó ń sáré ìje.
Ìjáde lọ rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wá
àti àyíká rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ rẹ̀;
kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore rẹ̀.

Pípé ni òfin OLúWA,
ó ń yí ọkàn padà.
Ẹ̀rí OLúWA dánilójú,
ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.
Ìlànà OLúWA tọ̀nà,
ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.
Àṣẹ OLúWA ni mímọ́,
ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.
Ìbẹ̀rù OLúWA mọ́,
ó ń faradà títí láéláé.
Ìdájọ́ OLúWA dájú
òdodo ni gbogbo wọn.

Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ,
ju wúrà tí o dára jùlọ,
wọ́n dùn ju oyin lọ,
àti ju afárá oyin lọ.Saamu 19:1-10 - Àwọn ọ̀run ń sọ nípa ti ògo Ọlọ́run;
Àwọsánmọ̀ ń sọ nípa ti iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
Wọ́n ń fọhùn ní ọjọ́ dé ọjọ́;
wọ́n ń fi ìmọ̀ hàn ní alẹ́ dé alẹ́.
Kò sí ohùn tàbí èdè
níbi tí a kò gbé gbọ́ ìró wọn
Ohùn wọn jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀ ayé,
ọ̀rọ̀ wọn títí dé òpin ilẹ̀ ayé.
Ó ti kọ́ àgọ́ fún oòrùn nínú àwọn ọ̀run.
Tí ó dàbí ọkọ ìyàwó tí ó ń jáde ti yàrá rẹ̀ wá,
òun yọ bí alágbára ọkùnrin tí ó ń sáré ìje.
Ìjáde lọ rẹ̀ ni láti òpin ọ̀run wá
àti àyíká rẹ̀ sì dé ìpínlẹ̀ rẹ̀;
kò sì sí ohun tí ó pamọ́ kúrò nínú oore rẹ̀.

Pípé ni òfin OLúWA,
ó ń yí ọkàn padà.
Ẹ̀rí OLúWA dánilójú,
ó sọ òpè di ọlọ́gbọ́n.
Ìlànà OLúWA tọ̀nà,
ó ń fi ayọ̀ fún ọkàn.
Àṣẹ OLúWA ni mímọ́,
ó ń fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú.
Ìbẹ̀rù OLúWA mọ́,
ó ń faradà títí láéláé.
Ìdájọ́ OLúWA dájú
òdodo ni gbogbo wọn.

Wọn ṣọ̀wọ́n ju wúrà lọ,
ju wúrà tí o dára jùlọ,
wọ́n dùn ju oyin lọ,
àti ju afárá oyin lọ.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Saamu 19:1-10