Saamu 18:37-50

Saamu 18:37-50 YCB

Èmi lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì bá wọn èmi kò sì padà lẹ́yìn wọn títí a fi run wọ́n. Èmi sá wọn ní ọgbẹ́ tí wọn ko fi le è dìde; Wọ́n ṣubú ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi. Nítorí ìwọ fi agbára dì mí ní àmùrè fún ogun náà; ìwọ ti mú àwọn tí ó dìde si mí tẹríba ní abẹ́ ẹsẹ̀ mi Ìwọ yí ẹ̀yìn àwọn ọ̀tá mí padà sí mi èmi sì pa àwọn tí ó kórìíra mi run. Wọ́n kígbe fún ìrànlọ́wọ́, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó gbà wọ́n, àní sí OLúWA, ṣùgbọ́n kò dá wọn lóhùn. Mo lù wọ́n gẹ́gẹ́ bí eruku níwájú afẹ́fẹ́; mo dà wọ́n síta gẹ́gẹ́ bí ẹrọ̀fọ̀. Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn; Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí, ni wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n pa àṣẹ mi mọ́; àwọn ọmọ àjèjì yóò tẹríba fún mi. Àyà yóò pá àlejò; wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn. OLúWA wà láààyè! Olùbùkún ni àpáta mi! Gbígbéga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi. Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbẹ̀san mi, tí ó sì ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní abẹ́ mi, tí ó pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mí. Ìwọ gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí mi lọ; lọ́wọ́ àwọn ènìyàn alágbára ni ìwọ ti gbà mí. Títí láéláé, èmi yóò máa yìn ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ OLúWA; Èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ. Ó fún ọba rẹ̀ ni ìṣẹ́gun ńlá; ó fi ìkáàánú àìṣẹ̀tàn fún ẹni ààmì òróró rẹ̀, fún Dafidi àti ìran rẹ̀ títí láé.