Saamu 148:1-14

Saamu 148:1-14 YCB

Ẹ fi ìyìn fún OLúWA. Ẹ fi ìyìn fún OLúWA láti ọ̀run wá, Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga. Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀ Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀ Ẹ fi ìyìn fún un, oòrùn àti òṣùpá Ẹ fi ìyìn fún un, gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀. Ẹ fi ìyìn fún un, ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run. Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ OLúWA nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já. Ẹ yin OLúWA láti ilẹ̀ ayé wá ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi àti ẹ̀yin ibú Òkun Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu, ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ; Òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèkéé, igi eléso àti gbogbo igi kedari, Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́: Àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé, Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé. Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ OLúWA nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀, ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli, àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.