Saamu 147

147
Saamu 147
1Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Nítorí ohun rere ni láti máa kọrin ìyìn sí Ọlọ́run wa,
ó yẹ láti kọrin ìyìn sí i!
2 Olúwa kọ́ Jerusalẹmu;
Ó kó àwọn Israẹli tí a lé sọnù jọ.
3Ó wo àwọn tí ọkàn wọ́n bàjẹ́ sàn
ó sì di ọgbẹ́ wọ́n.
4Ó ka iye àwọn ìràwọ̀
ó sì pe ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ
5Títóbi ni Olúwa wa ó sì pọ̀ ní agbára
òye rẹ̀ kò sì ní òpin.
6 Olúwa wa pẹ̀lú àwọn onírẹ̀lẹ̀
bẹ́ẹ̀ ni ó rẹ̀ àwọn ènìyàn búburú sílẹ̀.
7Fi ọpẹ́ kọrin sí Olúwa
fi ohun èlò orin olókùn yin Ọlọ́run.
8Ó fi ìkùùkuu bo àwọ̀ sánmọ̀
ó rọ òjò sí orílẹ̀ ayé
ó mú kí koríko hù lórí àwọn òkè
9Ó pèsè oúnjẹ fún àwọn ẹranko
àti fún àwọn ọmọ ẹyẹ ìwò ní ìgbà tí wọ́n bá ń ké.
10Òun kò ní inú dídùn nínú agbára ẹṣin
bẹ́ẹ̀ ni Òun kò ní ayọ̀ sí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin
11 Olúwa ni ayọ̀ nínú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
sí àwọn tí ó ní ìrètí nínú àánú rẹ̀.
12Yin Olúwa, ìwọ Jerusalẹmu
yin Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni.
13Nítorí tí ó ti mú ọ̀pá ìdábùú ibodè rẹ̀ lágbára;
Òun sì ti bùkún fún àwọn ọmọ rẹ̀ nínú rẹ
14Òun jẹ́ kí àlàáfíà wà ní àwọn ẹnu ibodè rẹ̀
òun sì fi jéró dáradára tẹ́ ọ lọ́rùn.
15Òun sì rán àṣẹ rẹ̀ sí ayé
ọ̀rọ̀ rẹ̀ sáré tete.
16Ó fi yìnyín fún ni bi irun àgùntàn
ó sì fọ́n ìrì dídì ká bí eérú
17Ó rọ òjò yìnyín rẹ̀ bí òkúta wẹ́wẹ́
ta ni ó lè dúró níwájú òtútù rẹ̀
18Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde ó sì mú wọn yọ̀
ó mú kí afẹ́fẹ́ rẹ̀ fẹ́
ó sì mú odò rẹ̀ sàn.
19Ó sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ di mí mọ̀ fún Jakọbu
àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀ fún Israẹli
20Òun kó tí ṣe irú èyí sí orílẹ̀-èdè kan rí, Bí ó ṣe ti ìdájọ́ rẹ̀
wọn ko mọ òfin rẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Saamu 147: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa