Saamu 111:1-10

Saamu 111:1-10 YCB

Ẹ máa yin OLúWA. Èmi yóò máa yin OLúWA pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi, ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn. Iṣẹ́ OLúWA tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀. Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo: àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé. Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí: OLúWA ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú. Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀: òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀. Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀ láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú. Wọ́n dúró láé àti láé, ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n. Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀: ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé: Mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀. Ìbẹ̀rù OLúWA ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n: òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀, ìyìn rẹ̀ dúró láé.