Òwe 8:24-26

Òwe 8:24-26 YCB

Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú; kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn, ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi, kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀ tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.