Òwe 20:13-15

Òwe 20:13-15 YCB

Má ṣe fẹ́ràn oorun, àìṣe bẹ́ẹ̀ ìwọ yóò di tálákà. Ma ṣe sùn ìwọ yóò sì ní oúnjẹ láti tún fi tọrọ. “Kò dára, kò dára” ní ẹni tó ra ọjà máa ń wí nígbà tí ó bá kúrò níbẹ̀ tán, yóò máa yangàn bí òun tí ṣe rí rà sí. Wúrà wà, iyùn sì wà rẹpẹtẹ ṣùgbọ́n, ahọ́n tí ń sọ ìmọ̀ gan an ni ọ̀ṣọ́ iyebíye.