Òwe 14:1-18

Òwe 14:1-18 YCB

Ọlọ́gbọ́n obìnrin kọ́ ilé e rẹ̀, ṣùgbọ́n aṣiwèrè obìnrin fi ọwọ́ ara rẹ̀ fà á lulẹ̀. Ẹni tí ń rìn déédé bẹ̀rù OLúWA, ṣùgbọ́n ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ kò tọ́ kẹ́gàn OLúWA. Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè a máa ṣokùnfà pàṣán fún ẹ̀yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó. Níbi tí kò sí ẹran, ibùjẹ ẹran a máa mọ́ tónítóní ṣùgbọ́n, nípa agbára akọ màlúù ni ọ̀pọ̀ ìkórè ti ń wá. Ẹlẹ́rìí tí ń ṣọ òtítọ́ kì í tan ni ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí èké a máa tú irọ́ jáde. Ẹlẹ́gàn ń wá ọgbọ́n kò sì rí rárá, ṣùgbọ́n ìmọ̀ máa ń wà fún olóye. Má ṣe súnmọ́ aláìgbọ́n ènìyàn, nítorí ìwọ kì yóò rí ìmọ̀ ní ètè rẹ̀. Ọgbọ́n olóye ni láti ronú jinlẹ̀ nípa ọ̀nà wọn ṣùgbọ́n ìwà òmùgọ̀ aṣiwèrè ni ìtànjẹ. Aláìgbọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ nígbà tí ó yẹ kí ó ṣe àtúnṣe ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ṣùgbọ́n láàrín àwọn olódodo ni a ti rí ojúrere. Ọkàn kọ̀ọ̀kan ló mọ ẹ̀dùn ọkàn tirẹ̀ kò sì ṣí ẹnìkan tó le è bá ọkàn mìíràn pín ayọ̀ rẹ̀. A ó pa ilé ènìyàn búburú run Ṣùgbọ́n àgọ́ olódodo yóò máa gbèrú sí i. Ọ̀nà kan wà tí ó dàbí i pé ó dára lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, a máa jásí ikú. Kódà nígbà tí a ń rẹ́rìn-ín, ọkàn le è máa kérora; ayọ̀ sì le è yọrí sí ìbànújẹ́. A ó san án lẹ́kùnrẹ́rẹ́ fún aláìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀, ènìyàn rere yóò sì gba èrè fún tirẹ̀. Òpè ènìyàn gba ohun gbogbo gbọ́ ṣùgbọ́n olóye ènìyàn ronú lórí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀. Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kórìíra ibi ṣùgbọ́n aláìgbọ́n jẹ́ alágídí àti aláìṣọ́ra. Ẹni tí ó máa ń tètè bínú máa ń hùwà aṣiwèrè, a sì kórìíra eléte ènìyàn. Òpè jogún ìwà òmùgọ̀ ṣùgbọ́n a dé ọlọ́gbọ́n ní adé ìmọ̀.