Bí ìwọ bá ní ìmúlọ́kànle nítorí pé ìwọ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi, bi ìtùnú kan bá wà nínú ìfẹ́ rẹ̀, bí ìdàpọ̀ Ẹ̀mí kan bá wà, bí ìyọ́nú àti ìṣeun bá wà, síbẹ̀ ẹ mú ayọ̀ mi kún nínú ìṣọ̀kan yín, nípa ìfẹ́ kan náà, wíwà ní ẹ̀mí kan náà àti ète kan náà. Ẹ má ṣe ohunkóhun nínú ìlépa ara tàbí ògo asán, ṣùgbọ́n ní ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn kí olúkúlùkù ro àwọn ẹlòmíràn sí ẹni ti ó sàn ju òun lọ.
Kà Filipi 2
Feti si Filipi 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Filipi 2:1-3
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò