Numeri Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìwé yìí jẹ́ ìtẹ̀síwájú ìwé Lefitiku. A fún un ní orúkọ láti ipasẹ̀ àkọsílẹ̀ ìkànìyàn tó wà nínú ìwé náà. Ó so ìṣẹ̀lẹ̀ ìrìnàjò àwọn ọmọ Israẹli láti Òkè Sinai pọ̀ títí wọ́n fi dé ilẹ̀ Moabu. Ó sọ nípa ti ìkùnsínú àti ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ènìyàn Ọlọ́run àti bí a ṣe ṣe ìdájọ́ wọn. Àwọn tí Ọlọ́run ti rà padà láti oko ẹrú Ejibiti, àwọn tí Ọlọ́run ti bá dá májẹ̀mú ní Òkè Sinai tí wọn kò fi ìgbàgbọ́, àti ìmoore, ìgbọ́ràn san án fún un bí kò ṣe àìgbàgbọ́, àìmoore àti ìṣọ̀tẹ̀ ìgbà gbogbo, èyí tí wọ́n ṣe nípa kíkọ̀ láti jagun gba ilẹ̀ Kenaani. Wọ́n pàdánù ipa wọn nínú ìlérí ilẹ̀ náà tí Ọlọ́run ti ṣe fún wọn. Àwọn ọmọ wọn ni wọ́n wá jẹ àǹfààní ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run tí ó jẹ́ tiwọn ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.
Ìwé yìí sọ lẹ́sẹẹsẹ bí àwọn ọmọ Israẹli ṣe rin ìrìnàjò wọn. Ní ọdún kìn-ín-ní lẹ́yìn tí a dá Israẹli ní ìdè kúrò ní oko ẹrú ní Ejibiti, wọ́n dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run ní Sinai láti jẹ́ ènìyàn ìjọba rẹ̀, èyí ni ó mú kí ó kọ́ àgọ́ rẹ̀ sí àárín wọn. Olúwa lo àwọn ọmọ Israẹli ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ogun. Bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n ń ṣẹ́gun lọ́tùn ún lósì nítorí Olúwa ni olórí ogun wọn, ó sì ń fẹ́ láti fi ẹsẹ̀ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ bí ó ti ṣèlérí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tókù láti gba ilẹ̀ àwọn ènìyàn tó ṣubú àti láti rà wọ́n padà.
Ó sọ nípa ìbínú Ọlọ́run tí ń bọ̀ lórí àwọn aláìgbọ́ràn ènìyàn. Nítorí ìṣọ̀tẹ̀ Israẹli nípa ìyẹ̀nà kúrò lórí májẹ̀mú Ọlọ́run. Kódà Mose, wòlíì ńlá a nì kò bọ́ lọ́wọ́ ìbínú Ọlọ́run nígbà tó ṣe àìgbọ́ràn sí i. Àwọn tí Ọlọ́run lò láti fi ẹsẹ̀ orílẹ̀-èdè múlẹ̀ ń kú tán kí orílẹ̀-èdè náà tó di tirẹ̀. Ìbéèrè ńlá tí a ó bi ara wa ni pé. Ṣe Ọlọ́run ti parí pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Israẹli ni? Ṣé àwọn ìlérí rẹ̀ ti wá di ohun àtijọ́ bí? Balaamu jẹ́ kí ó yé wa pé Olúwa kò yẹsẹ̀ lórí ìlérí rẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ aláìṣòdodo sí i.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Israẹli ní Sinai 1.1–10.10.
ii. Ìrìnàjò láti Sinai dé Kadeṣi 10.11–12.16.
iii. Israẹli ní Kadeṣi 13.1–20.13.
iv. Ìrìnàjò láti Kadeṣi dé Moabu 20.14–22.1.
v. Israẹli ní ilẹ̀ Moabu 22.2–32.42.
vi. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn 33–36.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Numeri Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀