Nehemiah 9:22-38

Nehemiah 9:22-38 YCB

“Ìwọ fi àwọn ìjọba àti àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ náà fún wọ́n. Wọ́n sì gba ilẹ̀ ọba Sihoni ará a Heṣboni àti ilẹ̀ Ogu ọba Baṣani. Ìwọ ti mú àwọn ọmọ wọn pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ tí o ti sọ fún àwọn baba wọn pé kí wọn wọ̀, kí wọn sì jogún un rẹ̀ Àwọn ọkùnrin wọn wọ inú rẹ̀, wọ́n sì gbà ilẹ̀ náà. Ìwọ sì tẹ orí àwọn ará a Kenaani, tí ń gbé inú ilẹ̀ náà ba níwájú wọn; ó fi àwọn ará a Kenaani lé wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ọba wọn àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kí wọn ṣe wọn bí ó ti wù wọ́n. Wọ́n gba àwọn ìlú olódi àti ilẹ̀ ọlọ́ràá; wọ́n gba àwọn ilé tí ó kún fún onírúurú gbogbo nǹkan rere, àwọn kànga tí a ti gbẹ́, àwọn ọgbà àjàrà, àwọn ọgbà olifi àti àwọn igi eléso ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. Wọ́n jẹ, wọ́n yó, wọ́n sì sanra dáradára; wọ́n sì yọ̀ nínú oore ńlá rẹ “Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe àìgbọ́ràn, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọ; wọ́n gbàgbé òfin rẹ. Wọ́n pa àwọn wòlíì rẹ, tí o fi gbà wọn ni ìyànjú pé kí wọn yí padà sí ọ; wọ́n sì se ọ̀rọ̀-òdì tí ó burú jàì. Nítorí náà, ìwọ fi wọ́n lé àwọn ọ̀tá wọn lọ́wọ́, àwọn tí ó ni wọ́n lára. Ṣùgbọ́n nígbà tí a ni wọ́n lára wọ́n kígbe sí ọ. Ìwọ gbọ́ wọn láti ọ̀run wá àti nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àánú rẹ, ìwọ fún wọn ní olùgbàlà, tí ó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. “Ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ti wà nínú ìsinmi, wọn a sì túnṣe búburú lójú rẹ. Nígbà náà ni ìwọ kọ̀ wọ́n sílẹ̀ ṣọ́wọ́ àwọn ọ̀tá kí wọ́n lè jẹ ọba lórí wọn. Nígbà tí wọ́n bá sì tún kígbe sí ọ, ìwọ a gbọ́ láti ọ̀run wá, àti nínú àánú rẹ ni ìwọ gbà láti ìgbà dé ìgbà. “Ìwọ kìlọ̀ fún wọn láti padà sínú òfin rẹ, ṣùgbọ́n wọ́n hu ìwà ìgbéraga, wọ́n sì ṣe àìgbọ́ràn si àṣẹ rẹ. Wọ́n ṣẹ̀ sí ìlànà rẹ, nípa èyí tí ènìyàn yóò yè tí wọ́n bá pa wọ́n mọ́. Nínú agídí ọkàn wọ́n kọ ẹ̀yìn sí ọ, wọ́n jẹ́ olórí kunkun wọn kò sì fẹ́ gbọ́. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni ìwọ fi ní sùúrù pẹ̀lú wọn. Nípa ẹ̀mí rẹ ni ìwọ kìlọ̀ fún wọn nípasẹ̀ àwọn wòlíì. Síbẹ̀ wọn kò fi etí sílẹ̀, nítorí náà ni ìwọ ṣe fi wọ́n lé àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n nínú ọ̀pọ̀ àánú rẹ, ìwọ kò mú òpin bá wọn tàbí kọ̀ wọ́n sílẹ̀, nítorí ìwọ ni Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú. “Ǹjẹ́ nítorí náà, Ọlọ́run wa, Ọlọ́run tí ó tóbi, tí ó lágbára, tí ó sì ní ẹ̀rù, ẹni tí ó pa májẹ̀mú ìfẹ́ mọ́, má ṣe jẹ́ gbogbo ìnira yìí dàbí ohun kékeré ní ojú rẹ—ìnira tí ó ti wá sórí wa, sórí àwọn ọba wa àti àwọn olórí wa, sórí àwọn àlùfáà wa àti àwọn wòlíì, sórí àwọn baba wa àti sórí gbogbo ènìyàn rẹ̀, láti àwọn ọjọ́ àwọn ọba Asiria wá títí di òní. Ìwọ jẹ́ olódodo nínú ohun gbogbo tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí wa; ìwọ sì ti ṣe òtítọ́, nígbà tí a bá ṣe búburú. Àwọn ọba wa, àwọn olórí wa, àwọn àlùfáà wa, àti àwọn baba wa kò tẹ̀lé òfin rẹ; wọn kò fetísílẹ̀ sí àṣẹ rẹ tàbí àwọn ìkìlọ̀ tí ìwọ fún wọn. Àní nígbà tí wọ́n wà nínú ìjọba wọn, tí wọ́n ń gbádùn oore ńlá tí ìwọ fi fún wọn, ní ilẹ̀ tí ó tóbi tí ó sì lọ́ràá, wọn kò sìn ọ́ tàbí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà búburú wọn. “Ṣùgbọ́n wò ó, àwa jẹ́ ẹrú lónìí, àwa jẹ́ ẹrú ní ilẹ̀ tí ìwọ fún àwọn baba ńlá wa, nítorí kí wọn bá máa jẹ èso rẹ̀ àti ìre mìíràn tí ó mú jáde. Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkórè rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọba tí ó fi ṣe olórí wa. Wọ́n ń ṣe àkóso lórí wa àti lórí ẹran wa bí ó ti wù wọ́n, àwa sì wà nínú ìpọ́njú ńlá. “Nítorí gbogbo èyí, a ń ṣe àdéhùn tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀, a sì kọ ọ́ sínú ìwé, àwọn olórí ọmọ Lefi àwọn àlùfáà sì fi èdìdì dì í.”