Bẹ́ẹ̀ ni àwa mọ odi náà títí gbogbo rẹ̀ fi dé ìdajì gíga rẹ̀, nítorí àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú gbogbo ọkàn an wọn.
Ṣùgbọ́n nígbà tí Sanballati, Tobiah, àwọn ará Arabia, ará Ammoni, àti àwọn ènìyàn Aṣdodu gbọ́ pé àtúnṣe odi Jerusalẹmu ti ga dé òkè àti pé a ti mọ àwọn ibi tí ó yá dí, inú bí wọn gidigidi. Gbogbo wọn jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti wá bá Jerusalẹmu jà àti láti dìde wàhálà sí í. Ṣùgbọ́n àwa gbàdúrà sí Ọlọ́run wa, a sì yan olùṣọ́ ọ̀sán àti ti òru láti kojú ìhàlẹ̀ yìí.
Lákòókò yìí, àwọn ènìyàn Juda wí pé, “Agbára àwọn òṣìṣẹ́ ti dínkù, àlàpà púpọ̀ ni ó wà tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi le è mọ odi náà.”
Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọ̀tá wa wí pé, “Kí wọn tó mọ̀ tàbí kí wọn tó rí wa, àwa yóò ti dé àárín wọn, a ó sì pa wọ́n, a ó sì dá iṣẹ́ náà dúró.”
Nígbà náà ni àwọn Júù tí ó ń gbé ní ẹ̀gbẹ́ wọn wá sọ fún wa ní ìgbà mẹ́wàá pé, “Ibikíbi tí ẹ̀yin bá padà sí, wọn yóò kọlù wá.”
Nítorí náà mo dá ènìyàn díẹ̀ dúró níbi tí ó rẹlẹ̀ jù lẹ́yìn odi ní ibi gbangba, mo fi wọ́n síbẹ̀ nípa àwọn ìdílé wọn, pẹ̀lú àwọn idà wọn, àwọn ọ̀kọ̀ wọn àti àwọn ọrun wọn. Lẹ́yìn ìgbà tí mo wo àwọn nǹkan yíká, mo dìde mo sì wí fún àwọn ọlọ́lá àwọn ìjòyè àti àwọn ènìyàn tókù pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù u wọn. Ẹ rántí OLúWA, ẹni tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù, kí ẹ sì jà fún àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, àwọn ìyàwó yín àti àwọn ilé yín.”