Bẹ̃ni awa mọ odi na: gbogbo odi na ni a si mọ kàn ara wọn titi de ida meji rẹ̀: nitori awọn enia na ni ọkàn lati ṣiṣẹ.
O si ṣe, nigbati Sanballati, ati Tobiah, ati awọn ara Arabia, ati awọn ara Ammoni, ati awọn ara Aṣdodi gbọ́ pe, a mọ odi Jerusalemu de oke, ati pe a bẹ̀rẹ si tun ibi ti o ya ṣe, inu wọn ru gidigidi.
Gbogbo wọn si jọ gbìmọ pọ̀ lati wá iba Jerusalemu jà, ati lati ṣe ika si i.
Ṣugbọn awa gba adura wa si Ọlọrun wa, a si yan iṣọ si wọn lọsan ati loru, nitori wọn.
Juda si wipe, Agbara awọn ti nru ẹrù dínkù, àlapa pupọ li o wà, tobẹ̃ ti awa kò fi le mọ odi na.
Awọn ọta wa si wipe, Nwọn kì yio mọ̀, bẹ̃ni nwọn kì yio ri titi awa o fi de ãrin wọn, ti a o fi pa wọn, ti a o si da iṣẹ na duro.
O si ṣe, nigbati awọn ara Juda ti o wà li agbegbe wọn de, nwọn wi fun wa nigba mẹwa pe, Lati ibi gbogbo wá li ẹnyin o pada tọ̀ wa wá.
Nitorina ni mo yàn awọn enia si ibi ti o rẹlẹ lẹhin odi, ati si ibi gbangba, mo tilẹ yàn awọn enia gẹgẹ bi idile wọn, pẹlu idà wọn, ọ̀kọ wọn, ati ọrun wọn.
Mo si wò, mo si dide, mo si wi fun awọn ìjoye, ati fun awọn olori, ati fun awọn enia iyokù pe, Ẹ máṣe jẹ ki ẹ̀ru wọn bà nyin, ẹ ranti Oluwa ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ki ẹ si jà fun awọn arakunrin nyin, awọn ọmọkunrin nyin, ati awọn ọmọbinrin nyin, awọn aya nyin, ati ile nyin.