Nahumu Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ìwé Nahumu kún fún ọ̀rọ̀-ìjìnlẹ̀ àti ìran. Nahumu túmọ̀ sí ìtùnú. Ó dojú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kọ ìṣubú Ninefe (1.1) Ninefe yìí dúró fún Asiria tó kọlu Samaria (722–721) tó sì ń dún mọ̀huru mọ Juda. Wọn a sì jẹ àwọn olórí ogun ìlú tiwọn ba ṣẹ́gun ní yà kí wọn tó pa wọ́n. Ìwà ipá, ìrẹ́nijẹ, àgbèrè, ìgbéraga, àti àwọn ìwà ìbàjẹ́ gbogbo sì gbilẹ̀ ní Ninefe tó jẹ́ olú ìlú Asiria.
Ìwé yìí tẹnumọ́ kókó kan pàtàkì, èyí tí ṣe ìdájọ́ Olúwa lórí ìlú Ninefe nítorí ìwà ìríra, àgbèrè, ìbọ̀rìṣà àti ìwà búburú wọn. A sì torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn pa ìlú náà run. Kì í ṣe pé Ọlọ́run ní àánú nìkan (Ro 11.22) ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ Ọlọ́run ẹlẹ́san. Ọlọ́run lọ́ra láti bínú, ó sì tóbi ní agbára, Ó jẹ́ ààbò fún àwọn ti ó gbẹ́kẹ̀lé (1.7) nígbà ìṣòro àti ní ọjọ́ ìpọ́njú, ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ó rí òun kò ni fi àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀ láìjìyà ẹ̀ṣẹ̀. Òdodo ní ń gbe orílẹ̀-èdè lékè, ìlú ti a fi ipá, ìwà ìka ṣe ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóò ṣubú. Nahumu sọ nípa bí títóbi Ọlọ́run ṣe kárí gbogbo ayé. Ọlọ́run ni Olúwa gbogbo ayé, òun sì ló ń darí ìpín ènìyàn.
Kókó-ọ̀rọ̀
Àkọlé
i. A ṣe ìdájọ́ lórí Ninefe 1.1-15.
ii. Ìdájọ́ Ninefe 2.1.
iii. A pa Ninefe run pátápátá 3.19.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Nahumu Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀