Jesu sì tún bẹ̀rẹ̀ sí ń kọ́ni létí Òkun Àwọn ìjọ ènìyàn tí ó yí i ká pọ̀ jọjọ tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, tí ó sì jókòó nínú rẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun, nígbà tí àwọn ènìyàn sì wà ní ilẹ̀ létí Òkun. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé: “Ẹ fi etí sílẹ̀! Ní ọjọ́ kan, afúnrúgbìn kan jáde lọ láti lọ fúnrúgbìn rẹ̀. Bí ó ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ. Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ àpáta, níbi tí erùpẹ̀ ko sí púpọ̀. Láìpẹ́ ọjọ́, ó hu jáde. Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn mú gangan, ó jóná, nítorí tí kò ní gbòǹgbò, ó gbẹ. Àwọn irúgbìn mìíràn sì bọ́ sáàrín ẹ̀gún, nígbà tí ẹ̀gún sì dàgbàsókè, ó fún wọn pa, tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn irúgbìn náà kò le so èso. Ṣùgbọ́n òmíràn bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, o sì so èso lọ́pọ̀lọpọ̀-òmíràn ọgbọọgbọ̀n, òmíràn ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún.”
Jesu sì wí pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”
Nígbà tí ó ku òun nìkan pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá àti àwọn mìíràn, wọ́n bi í léèrè wí pé, “Kí ni ìtumọ̀ òwe rẹ̀?” Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin ni a gbà láààyè láti mọ ohun ìjìnlẹ̀ nípa ìjọba Ọlọ́run. Èyí tí ó pamọ́ sí àwọn tí ó wà lẹ́yìn agbo ìjọba náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé,
“ ‘wọn yóò rí i, wọn yóò sì gbọ́, kì yóò yé wọn,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì yípadà sí Ọlọ́run.
Tàbí kí a dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n!’ ”
Ṣùgbọ́n Jesu wí fún wọn pé, “Bí òwe tí ó rọrùn yìí kò bá yé e yín? Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe mọ ìtumọ̀ àwọn mìíràn tí mo ń sọ fún un yín? Afúnrúgbìn ń fúnrúgbìn ọ̀rọ̀ náà. Àwọn èso tó bọ́ sí ojú ọ̀nà, ni àwọn ọlọ́kàn líle tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, lójúkan náà èṣù wá ó sì mú kí wọn gbàgbé ohun tí wọ́n ti gbọ́. Bákan náà, àwọn tí ó bọ́ sórí àpáta, ni àwọn ènìyàn tí wọ́n fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n kò ni gbòǹgbò tí ó jinlẹ̀ ní ọkàn wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n á wà fún ìgbà díẹ̀, lẹ́yìn náà nígbà ti wàhálà tàbí inúnibíni bá dìde nítorí ọ̀rọ̀ náà, lójúkan náà, wọ́n á kọsẹ̀. Àwọn tí ó bọ́ sáàrín ẹ̀gún ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí wọn sì gbà á. Ṣùgbọ́n láìpẹ́ jọjọ, àwọn adùn ayé àti inú dídùn, ọrọ̀ àti ìjàkadì fún àṣeyọrí àti ìfẹ́ àwọn ohun mèremère ayé, gba ọkàn wọn, wọ́n sì fún ọ̀rọ̀ náà pa ní ọkàn wọn. Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ aláìléso. Ṣùgbọ́n àwọn tí ó bọ́ sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, ní àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì gbà á lóòtítọ́, wọ́n sì mú èso púpọ̀ jáde fún Ọlọ́run ní ọgbọọgbọ̀n, ọgọọgọ́ta, àti òmíràn ọgọọgọ́rùn-ún, gẹ́gẹ́ bí a ti gbìn ín sí ọkàn wọn.”
Ó sì wí fún wọn pé, “A ha lè gbé fìtílà wá láti fi sábẹ́ òṣùwọ̀n tàbí sábẹ́ àkéte? Rárá o, ki a ṣe pe a o gbé e ka orí ọ̀pá fìtílà? Gbogbo ohun tí ó pamọ́ nísinsin yìí yóò hàn ní gbangba ní ọjọ́ kan, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí ó wà ní ìkọ̀kọ̀, bí kò ṣe pé kí ó le yọ sí gbangba. Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́.”
Ó sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ẹ máa kíyèsi ohun tí ẹ bà gbọ́ dáradára, nítorí òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin bá fi wọ́n náà ni a ó fi wọ́n fún un yín àti jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí ẹni tí ó bá ní, òun ni a ó tún fi fún sí i àti lọ́wọ́ ẹni tí kò bá ní, ni a ó ti gba èyí náà tí ó ní.”