Ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ òfin ti ó dúró níbẹ̀ tí ó sì fetísílẹ̀ dáradára sí àròyé yìí ṣàkíyèsí pé, Jesu ti dáhùn dáradára. Òun pẹ̀lú sì béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Nínú gbogbo òfin, èwo ló ṣe pàtàkì jùlọ?”
Jesu dá ọkùnrin yìí lóhùn pé, “Èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwọn òfin ni èyí tí ó kà báyìí pé: ‘Gbọ́ Israẹli; Olúwa Ọlọ́run wa Olúwa kan ni. Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ẹ̀mí rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, èyí ní òfin kìn-ín-ní.’ Èkejì ni pé: ‘Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tó ga ju méjèèjì yìí lọ.”
Olùkọ́ òfin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, ìwọ sọ òtítọ́ nípa pé Ọlọ́run kan ni ó ń bẹ, àti pé kò sí òmíràn àfi òun nìkan. Àti kí a fi gbogbo àyà, àti gbogbo òye, àti gbogbo ọkàn àti gbogbo agbára fẹ́ ẹ, àti fẹ́ ọmọnìkejì ẹni bí ara ẹni, ó ju gbogbo ẹbọ sísun, àti ẹbọ lọ.”
Jesu rí i dájú pé òye ọkùnrin yìí ga, nítorí náà, Jesu sọ fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ kò jìnà sí à ti dé ìjọba Ọ̀run.” Láti ìgbà náà lọ, ẹnikẹ́ni kò tún béèrè ohun kan lọ́wọ́ Jesu.
Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jesu ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú tẹmpili, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí àwọn olùkọ́ òfin fi gbà wí pé Kristi náà ní láti jẹ́ ọmọ Dafidi? Nítorí tí Dafidi tìkára rẹ̀, ti ń ti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ sọ̀rọ̀ wí pé:
“ ‘Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:
“Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,
títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.” ’
Níwọ́n ìgbà tí Dafidi tìkára rẹ̀ pè é ní ‘Olúwa,’ Báwo ni ó túnṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ó sì wí fún wọn nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra fun àwọn olùkọ́ òfin tí wọ́n fẹ́ láti máa wọ aṣọ gígùn káàkiri, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu àti ipò ọlá níbi àsè. Àwọn tí wọ́n jẹ ilé àwọn opó rún, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn, nítorí èyí, ìjìyà wọn yóò pọ̀ púpọ̀.”
Jesu jókòó ní òdìkejì kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i. Ṣùgbọ́n obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ owó idẹ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdá méjì owó-babà kan sínú rẹ̀.
Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, tálákà opó yìí sọ sínú àpótí ìṣúra ju gbogbo àwọn ìyókù to sọ sínú rẹ lọ. Nítorí pé, àwọn ìyókù mú nínú ọ̀pọ̀ ìní wọ́n, ṣùgbọ́n ní tirẹ̀, nínú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní náà sílẹ̀ àní gbogbo ìní rẹ̀.”