Marku 1:1-15

Marku 1:1-15 YCB

Ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere nípa Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé wòlíì Isaiah pé: “Èmi yóò ran oníṣẹ́ mi síwájú rẹ, Ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe.” “Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ” Johanu dé, ẹni tí ó ń tẹnibọmi ní aginjù, tí ó sì ń wàásù ìtẹ̀bọmi ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní agbègbè Judea, àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, a sì ti ọwọ́ rẹ̀ tẹ gbogbo wọn bọ omi ni odò Jordani, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Johanu sì wọ aṣọ irun ìbákasẹ. Ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù wí pé, “Ẹnìkan tí ó tóbi jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, okùn bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó ẹni tí ń tú. Èmi ń fi omi ṣe ìtẹ̀bọmi yín, ṣùgbọ́n Òun yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ìtẹ̀bọmi yín.” Ó sì ṣe ní ọjọ́ kan Jesu ti Nasareti ti Galili jáde wá, a sì ti ọwọ́ Johanu ṣe ìtẹ̀bọmi fún ní odò Jordani. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí Jesu ń ti inú omi jáde wá, ó rí ọ̀run tí ó ṣí sílẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ bí àdàbà sọ̀kalẹ̀ lé e lórí. Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.” Lẹ́sẹ̀kan náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jesu sí ijù, Ó sì wà ní ogójì ọjọ́ ní aginjù. A sì ti ọwọ́ Satani dán an wò, ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́. Àwọn angẹli sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un. Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Herodu ti fi Johanu sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jesu lọ sí Galili, ó ń wàásù ìhìnrere ti ìjọba Ọlọ́run. Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìhìnrere yìí gbọ́.”

Àwọn fídíò fún Marku 1:1-15