Mika Ìfáàrà

Ìfáàrà
Ọ̀rọ̀ Mika wà láàrín ìdájọ́ ìparun àti ìdájọ́ ìrètí. Pàtàkì ohun tí ìwé yìí ṣàlàyé ni ìdájọ́ àti ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ Ọlọ́run. Mika sì tún tẹnumọ́ ọn pé Ọlọ́run kórìíra ìbọ̀rìṣà, ìdájọ́ èké, ìṣọ̀tẹ̀ àti ẹbọ asán, ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn láti máa dáríjì onírẹ̀lẹ̀.
Mika ṣe ìtẹnumọ́ pé ìdájọ́ àti ìtúsílẹ̀ wá nípasẹ̀ Ọlọ́run. Ó sì tún ṣàlàyé pé, Sioni yóò ni ògo ńlá ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Ìjọba Dafidi yóò wà ní ìkẹyìn, yóò sì ni ìwọ̀n tó pọ̀ nípasẹ̀ Messia tó ń bọ̀. Ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wí pé, “Ó ti fihàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí í ṣe rere, àti ohun tí Olúwa ń béèrè lọ́wọ́ rẹ?” (6.8)
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ Mika wá 1.1.
ii. Ìdájọ́ lórí Israẹli àti Juda 1.2–3.12.
iii. Ìrètí fún Israẹli àti Juda 4.1–5.15.
iv. Ẹ̀sùn Olúwa sí àwọn ọmọ Israẹli 6.1.
v. Ìbànújẹ́ yípadà sí ayọ̀ ìṣẹ́gun 7.20.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Mika Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀