Matiu 17:10-27

Matiu 17:10-27 YCB

Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ́ pé, “Kí ni ó fà á tí àwọn olùkọ́ òfin fi ń wí pé, Elijah ní láti kọ́ padà wá?” Jesu sì dáhùn pé, “Dájúdájú òtítọ́ ni wọ́n ń sọ. Elijah wá láti fi gbogbo nǹkan sí ipò. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín lóòótọ́; Elijah ti dé. Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ ọ́n, ọ̀pọ̀ tilẹ̀ hu ìwà búburú sí i. Bákan náà, Ọmọ ènìyàn náà yóò jìyà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú.” Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ̀ pé ó n sọ̀rọ̀ nípa Johanu onítẹ̀bọmi fún wọn ni. Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ ìjọ ènìyàn, ọkùnrin kan tọ̀ Jesu wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa, ṣàánú fún ọmọ mi, nítorí tí ó ní wárápá. Ó sì ń joró gidigidi, nígbà púpọ̀ ni ó máa ń ṣubú sínú iná tàbí sínú omi. Mo sì ti mú un tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò lè wò ó sàn.” Jesu sì dáhùn wí pé, “A! Ẹ̀yìn alágídí ọkàn àti aláìgbàgbọ́ ènìyàn, èmi yóò ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi ó sì ti fi ara dà á fún yín tó? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín yìí.” Nígbà náà ni Jesu bá ẹ̀mí èṣù tí ó ń bẹ nínú ọmọkùnrin náà wí, ó sì fi í sílẹ̀, à mú ọmọkùnrin náà láradá láti ìgbà náà lọ. Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi Jesu níkọ̀kọ̀ pé, “Èéṣe tí àwa kò lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde?” Jesu sọ fún wọn pé, “Nítorí ìgbàgbọ́ yín kéré. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin, bí ẹ bá ni ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ kéré bí hóró musitadi, ẹ̀yin lè wí fún òkè yìí pé, ‘Sípò kúrò níhìn-ín yìí,’ òun yóò sì ṣí ipò. Kò sì ní sí ohun tí kò ní í ṣe é ṣe fún yín.” Ṣùgbọ́n irú ẹ̀mí èṣù yìí kò ní lọ, bí kò ṣe nípa àwẹ̀ àti àdúrà. Nígbà tí wọ́n sì ti wà ní Galili, Jesu sọ fún wọn pé, “Láìpẹ́ yìí a ó fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́. Wọn yóò sì pa á, ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn èyí, yóò sì jí dìde sí ìyè.” Ọkàn àwọn Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì kún fún ìbànújẹ́ gidigidi. Nígbà tí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì dé Kapernaumu, àwọn agbowó òde tí ń gba owó idẹ méjì tó jẹ́ owó tẹmpili tọ Peteru wá wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ olùkọ́ yín ń san owó tẹmpili?” Peteru sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń san.” Nígbà tí Peteru wọ ilé láti bá Jesu sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, Jesu ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, Jesu bí i pé, “Kí ni ìwọ rò, Simoni? Ǹjẹ́ àwọn ọba ayé ń gba owó orí lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn tàbí lọ́wọ́ àwọn àlejò?” Peteru dáhùn pé, “Lọ́wọ́ àwọn àlejò ni.” Jesu sì tún wí pé, “Èyí jẹ́ wí pé àwọn ọmọ onílẹ̀ kì í san owó òde? Síbẹ̀síbẹ̀, àwa kò fẹ́ mú wọn bínú. Nítorí náà, ẹ lọ sí etí Òkun, kí ẹ sì sọ ìwọ̀ sí omi. Ẹ mú ẹja àkọ́kọ́ tí ẹ kọ́ fà sókè, ẹ ya ẹnu rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì rí owó idẹ kan níbẹ̀, ki ẹ fi fún wọn fún owó orí tèmi àti tirẹ̀.”

Àwọn fídíò fún Matiu 17:10-27