Mat 17:10-27

Mat 17:10-27 YBCV

Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn akọwe ha fi wipe, Elijah ni yio tètekọ de? Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Lõtọ ni, Elijah yio tètekọ de, yio si mu nkan gbogbo pada si ipò. Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, Elijah ti de na, nwọn kò si mọ̀ ọ, ṣugbọn nwọn ti ṣe ohunkohun ti o wù wọn si i. Gẹgẹ bẹ̃ na pẹlu li Ọmọ-enia yio jìya pupọ̀ lọdọ wọn. Nigbana li o yé awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Johanu Baptisti li ẹniti o nsọ̀rọ rẹ̀ fun wọn. Nigbati nwọn si de ọdọ ijọ enia, ọkunrin kan si tọ ọ wá, o kunlẹ fun u, o si wipe, Oluwa, ṣãnu ọmọ mi, nitori o ni warapa, o si njoro gidigidi: nigba pupọ ni ima ṣubu sinu iná, ati nigba pupọ sinu omi. Mo si mu u tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ wá, nwọn kò si le mu u larada. Jesu si dahùn, o wipe, A! iran alaigbàgbọ́ ati arekereke yi, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti mu sũru fun nyin pẹ to? Gbé ọmọ na tọ̀ mi wá nihin. Jesu si ba a wi, ẹmi èṣu na si jade kuro lara rẹ̀; a si mu ọmọ na larada ni wakati kanna. Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá lẹhin, nwọn bi i pe, Ẽṣe ti awa kò fi le lé e jade? Jesu si wi fun wọn pe, Nitori aigbagbọ́ nyin ni: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́ bi wóro irúgbin mustardi, ẹnyin o wi fun òke yi pe, Ṣi nihin lọ si ọ̀hun, yio si ṣi; kò si si nkan ti ẹ ki yio le ṣe. Ṣugbọn irú eyi ki ijade lọ bikoṣe nipa adura ati àwẹ̀. Nigbati nwọn mbẹ ni Galili, Jesu wi fun wọn pe, A o fi Ọmọ-enia le awọn enia lọwọ: Nwọn o si pa a, ni ijọ kẹta yio si jinde. Inu wọn si bajẹ gidigidi. Nigbati nwọn de Kapernaumu, awọn ti ngbà owodè tọ̀ Peteru wá, wipe, olukọ nyin ki isan owodè? O wipe, Bẹ̃ni. Nigbati o si wọ̀ ile, Jesu ṣiwaju rẹ̀, o bi i pe, Simoni, iwọ ti rò o si? lọwọ tali awọn ọba aiye ima gbà owodè? lọwọ awọn ọmọ wọn, tabi lọwọ awọn alejò? Peteru wi fun u pe, Lọwọ awọn alejò. Jesu wi fun u pe, Njẹ awọn ọmọ bọ́. Ṣugbọn ki a má bã bí wọn ninu, iwọ lọ si okun, ki o si sọ ìwọ si omi, ki o si mu ẹja ti o ba kọ́ fà soke; nigbati iwọ ba si yà a li ẹnu, iwọ o ri ṣekeli kan nibẹ̀: on ni ki o mu, ki o si fifun wọn fun temi ati tirẹ.

Àwọn fídíò fún Mat 17:10-27