Matiu 13:34-58

Matiu 13:34-58 YCB

Òwe ni Jesu fi sọ nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ènìyàn, òwe ni ó fi bá wọn sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tó sọ. Kí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì sọ lé wá sí ìmúṣẹ pé: “Èmi yóò ya ẹnu mi láti fi òwe sọ̀rọ̀. Èmi yóò sọ àwọn ohun tí ó fi ara sin láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá.” Lẹ́yìn náà ó sì fi ọ̀pọ̀ ènìyàn sílẹ̀ lóde, ó wọ ilé lọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọn wí pé, “Ṣàlàyé òwe èpò inú oko fún wa.” Ó sì dá wọn lóhùn pé, “Ọmọ ènìyàn ni ẹni tí ó ń fúnrúgbìn rere. Ayé ni oko náà; irúgbìn rere ni àwọn ènìyàn ti ìjọba ọ̀run. Èpò ni àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ti èṣù, ọ̀tá tí ó gbin àwọn èpò sáàrín alikama ni èṣù. Ìkórè ni òpin ayé, àwọn olùkórè sì ní àwọn angẹli. “Gẹ́gẹ́ bí a ti kó èpò jọ, tí a sì sun ún nínú iná, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Ọmọ Ènìyàn yóò ran àwọn angẹli rẹ̀, wọn yóò sì kó gbogbo ohun tó ń mú ni dẹ́ṣẹ̀ kúrò ní ìjọba rẹ̀ àti gbogbo ènìyàn búburú. Wọn yóò sì sọ wọ́n sí inú iná ìléru, níbi ti ẹkún òun ìpayínkeke yóò gbé wà. Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò máa ràn bí oòrùn ní ìjọba Baba wọn. Ẹni tí ó bá létí, jẹ́ kí ó gbọ́. “Ìjọba ọ̀run sì dàbí ìṣúra kan tí a fi pamọ́ sínú oko. Nígbà tí ọkùnrin kan rí i ó tún fi í pamọ́. Nítorí ayọ̀ rẹ̀, ó ta gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó ra oko náà. “Bákan náà ni ìjọba ọ̀run dàbí oníṣòwò kan tí ó ń wá òkúta olówó iyebíye láti rà. Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó ni iye lórí, ó lọ láti ta gbogbo ohun ìní rẹ̀ láti le rà á. “Bákan náà, a sì tún lè fi ìjọba ọ̀run wé àwọ̀n kan tí a jù sínú odò, ó sì kó onírúurú ẹja. Nígbà tí àwọ̀n náà sì kún, àwọn apẹja fà á sókè sí etí bèbè Òkun, wọ́n jókòó, wọ́n sì ṣa àwọn èyí tí ó dára sínú apẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n da àwọn tí kò dára nù. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn angẹli yóò wá láti ya àwọn ènìyàn búburú kúrò lára àwọn olódodo. Wọn ó sì ju àwọn ènìyàn búburú sínú iná ìléru náà, ní ibi ti ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.” Jesu bí wọn léèrè pé, “Ǹjẹ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí yé yín.” Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó yé wa.” Ó wí fún wọn pé, “Nítorí náà ni olúkúlùkù olùkọ́ òfin tí ó ti di ọmọ-ẹ̀yìn ní ìjọba ọ̀run ṣe dàbí ọkùnrin kan tí í ṣe baálé ilé, tí ó mú ìṣúra tuntun àti èyí tí ó ti gbó jáde láti inú yàrá ìṣúra rẹ̀.” Lẹ́yìn ti Jesu ti parí òwe wọ̀nyí, ó ti ibẹ̀ kúrò. Ó wá sí ìlú òun tìkára rẹ̀, níbẹ̀ ni ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú Sinagọgu, ẹnu sì yà wọ́n. Wọ́n béèrè pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí ti mú ọgbọ́n yìí àti iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí wá? Kì í ha ṣe ọmọ gbẹ́nàgbẹ́nà ni èyí bí? Ìyá rẹ̀ ha kọ́ ni à ń pè ní Maria bí? Arákùnrin rẹ̀ ha kọ́ ni Jakọbu, Josẹfu, Simoni àti Judasi bí? Àwọn arábìnrin rẹ̀ gbogbo ha kọ́ ni ó ń bá wa gbé níhìn-ín yìí, nígbà náà níbo ni ọkùnrin yìí ti rí àwọn nǹkan wọ̀nyí?” Inú bí wọn sí i. Ṣùgbọ́n Jesu wí fún wọn pé, “Wòlíì a máa lọ́lá ní ibòmíràn, àfi ní ilé ara rẹ̀ àti ní ìlú ara rẹ̀ nìkan ni wòlíì kò ti lọ́lá.” Nítorí náà kò ṣe iṣẹ́ ìyanu kankan níbẹ̀, nítorí àìnígbàgbọ́ wọn.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ