“Wò ó, Èmi yóò ran ìránṣẹ́ mi, yóò tún ọ̀nà ṣe ṣáájú mi. Nígbà náà ni OLúWA, tí ẹ̀yin ń wa, yóò dé ni òjijì sí tẹmpili rẹ̀; àní oníṣẹ́ májẹ̀mú náà, tí inú yín dùn sí, yóò dé,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. Ṣùgbọ́n ta ni o lè fi ara da ọjọ́ dídé rẹ̀? Ta ni yóò sì dúró nígbà tí ó bá fi ara hàn? Nítorí òun yóò dàbí iná ẹni tí ń da fàdákà àti bi ọṣẹ alágbàfọ̀: Òun yóò sì jókòó bí ẹni tí n yọ́, tí ó sì ń da fàdákà; yóò wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, yóò sì tún wọn dàbí wúrà àti fàdákà, kí wọn bá a lè mú ọrẹ òdodo wá fún OLúWA, nígbà náà ni ọrẹ Juda àti ti Jerusalẹmu yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún OLúWA, gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ àtijọ́, àti gẹ́gẹ́ bí ọdún ìgbàanì. “Èmi ó sì súnmọ́ yin fún ìdájọ́. Èmi yóò sì yára ṣe ẹlẹ́rìí sí àwọn oṣó, sí àwọn panṣágà, sí àwọn abúra èké, àti àwọn tí ó fi ọ̀yà alágbàṣe pọn wọn lójú, àti àwọn tí ó ni àwọn opó àti àwọn aláìní baba lára, àti sí ẹni tí kò jẹ́ kí àjèjì rí ìdájọ́ òdodo gbà, tí wọn kò sì bẹ̀rù mi,” ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí.
Kà Malaki 3
Feti si Malaki 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Malaki 3:1-5
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò