Nígbà tí ó sì ba gbogbo rẹ̀ jẹ́ tan, ìyàn ńlá wá mú ní ilẹ̀ náà; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí di aláìní. Ó sì fi ara rẹ sọfà fun ọ̀kan lára àwọn ọmọ ìlú náà; òun sì rán an lọ sí oko rẹ̀ láti tọ́jú ẹlẹ́dẹ̀. Ayọ̀ ni ìbá fi jẹ oúnjẹ tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ ní àjẹyó: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni kò sì fi fún un. “Ṣùgbọ́n nígbà tí ojú rẹ̀ wálẹ̀, ó ní ‘Mélòó mélòó àwọn alágbàṣe baba mí ni ó ní oúnjẹ àjẹyó, àti àjẹtì, èmi sì ń kú fún ebi níhìn-ín. Èmi ó dìde, èmi ó sì tọ baba mi lọ, èmi ó sì wí fún un pé: Baba, èmí ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ̀run, àti níwájú rẹ; Èmi kò sì yẹ, ní ẹni tí à bá pè ní ọmọ rẹ mọ́; fi mí ṣe ọ̀kan nínú àwọn alágbàṣe rẹ.’ Ó sì dìde, ó sì tọ baba rẹ̀ lọ. “Ṣùgbọ́n nígbà tí ó sì wà ní òkèrè, baba rẹ̀ rí i, àánú ṣe é, ó sì súré, ó rọ̀ mọ́ ọn ní ọrùn, ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.
Kà Luku 15
Feti si Luku 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Luku 15:14-20
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò