Lefitiku 22:17-33

Lefitiku 22:17-33 YCB

OLúWA sọ fún Mose pé, “Sọ fún Aaroni, àwọn ọmọ rẹ̀ àti fún gbogbo Israẹli kí o sì wí fún wọn pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín yálà ọmọ Israẹli ni tàbí àlejò tí ń gbé ní Israẹli bá mú ẹ̀bùn wá fún ọrẹ ẹbọ sísun sí OLúWA, yálà láti san ẹ̀jẹ́ tàbí ọrẹ àtinúwá. Ẹ gbọdọ̀ mú akọ láìní àbùkù láti ara màlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́, kí ó ba à lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín. Ẹ má ṣe mú ohunkóhun tí ó ní àbùkù wá, torí pé kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín. Bí ẹnikẹ́ni bá mú ọrẹ àlàáfíà wá láti inú agbo màlúù tàbí ti àgùntàn, fún OLúWA láti san ẹ̀jẹ́ pàtàkì tàbí fún ọrẹ àtinúwá. Ó gbọdọ̀ jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láìní àbùkù. Ẹ má ṣe fi ẹranko tí ó fọ́jú, tí ó fi ara pa, tí ó yarọ, tí ó ní kókó, tí ó ní èkúkú, èépá àti egbò kíkẹ̀ rú ẹbọ sí OLúWA. Ẹ kò gbọdọ̀ gbé èyíkéyìí nínú wọn sórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bi ọrẹ tí a fi iná ṣe sí OLúWA. Ẹ le mú màlúù tàbí àgùntàn tí ó ní àbùkù tàbí tí ó yọ iké wá fún ọrẹ àtinúwá, ṣùgbọ́n kò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ ẹ̀jẹ́. Ẹ má ṣe fi ẹranko tí kóró ẹpọ̀n rẹ̀ fọ́ tàbí tí a tẹ̀, tàbí tí a yà tàbí tí a là rú ẹbọ sí OLúWA. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí ní ilẹ̀ yín. Ẹ kò gbọdọ̀ gba irú ẹranko bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àlejò kankan láti fi rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ sí Ọlọ́run yín. A kò nígbà wọ́n fún yín nítorí pé wọ́n ní àbùkù, wọ́n sì díbàjẹ́.’ ” OLúWA sọ fún Mose pé, “Nígbà tí màlúù bá bímọ, tí àgùntàn bímọ, tí ewúrẹ́ sì bímọ, ọmọ náà gbọdọ̀ wà pẹ̀lú ìyá rẹ̀ fún ọjọ́ méje. Láti ọjọ́ kẹjọ ni ó ti di ìtẹ́wọ́gbà fún ọrẹ àfinásun sí OLúWA. Ẹ má ṣe pa màlúù àti ọmọ rẹ̀ tàbí àgùntàn àti ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà. “Nígbà tí ẹ bá rú ẹbọ ọpẹ́ sí OLúWA, ẹ rú u ní ọ̀nà tí yóò fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín. Ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ọjọ́ náà gan an: Ẹ má ṣe ṣẹ́ ọ̀kankan kù di àárọ̀. Èmi ni OLúWA. “Ẹ pa òfin mi mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni OLúWA. Ẹ má ṣe ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Àwọn ọmọ Israẹli gbọdọ̀ mọ̀ mí ní mímọ́. Èmi ni OLúWA tí ó sọ yín di mímọ́. Tí ó sì mú yín jáde láti Ejibiti wá láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni OLúWA.”