Nítorí ìfẹ́ OLúWA tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé, nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà. Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀; títóbi ni òdodo rẹ̀. Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni OLúWA; nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́. Dídára ni OLúWA fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí àwọn tí ó ń wá a. Ó dára kí a ní sùúrù fún ìgbàlà OLúWA. Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà nígbà tí ó wà ní èwe. Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, nítorí OLúWA ti fi fún un. Jẹ́ kí ó bo ojú rẹ̀ sínú eruku— ìrètí sì lè wà. Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a, sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì. Ènìyàn kò di ìtanù lọ́dọ̀ Olúwa títí láé. Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn, nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀. Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.
Kà Ẹkun Jeremiah 3
Feti si Ẹkun Jeremiah 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Ẹkun Jeremiah 3:22-33
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò