Juda Ìfáàrà

Ìfáàrà
A kọ lẹ́tà yìí láti ọwọ́ Juda. Juda ń rọ àwọn Kristiani láti dúró ṣinṣin, àti láti dojúkọ àwọn olùkọ́ èké àti ẹ̀kọ́ èké tí wọ́n mú wá. Juda gúnlẹ̀ ìwé rẹ̀ nípa gbígba àwọn Kristiani ní ìyànjú láti dúró ṣinṣin nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí kò ní jẹ́ kí a ṣubú.
Ewu tó wà nínú ẹ̀kọ́ èké àti bí ó ti ṣe pàtàkì kí ìjọ Ọlọ́run máa fi ojú ṣọ́ orí ni kókó ìwé yìí. Juda fẹ́ kí a gbé ohun tí ẹlòmíràn ń sọ yẹ̀ wò, àti irú ayé tí wọn ń gbé kí a bá à yan èyí tí ó dára tó sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìkíni 1-2.
ii. Ìkìlọ̀ lórí àwọn olùkọ́ èké 3-7.
iii. Ìgbé ayé búburú àwọn olùkọ́ èké 8-19.
iv. Ọ̀rọ̀ ìyànjú fún àwọn Kristiani 20-23.
v. Àdúrà fún ìbùkún Ọlọ́run 24-25.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Juda Ìfáàrà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀