Joṣua 10:12-14

Joṣua 10:12-14 YCB

Ní ọjọ́ tí OLúWA fi àwọn ọmọ Amori lé Israẹli lọ́wọ́, Joṣua sọ fún OLúWA níwájú àwọn ará Israẹli: “Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní orí Gibeoni, Ìwọ òṣùpá, dúró jẹ́ẹ́ lórí Àfonífojì Aijaloni.” Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn náà sì dúró jẹ́ẹ́, òṣùpá náà sì dúró, títí tí ìlú náà fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú ìwé Jaṣari. Oòrùn sì dúró ní agbede-méjì ọ̀run, kò sì wọ̀ ní ìwọ̀n odindi ọjọ́ kan. Kò sí ọjọ́ tí o dàbí rẹ̀ ṣáájú tàbí ní ẹ̀yìn rẹ̀, ọjọ́ tí OLúWA gbọ́ ohùn ènìyàn. Dájúdájú OLúWA jà fún Israẹli!