Jobu 25

25
Ìdáhùn Bilidadi
1Nígbà náà ní Bilidadi, ará Ṣuhi, dáhùn wí pé:
2“Ìjọba àti ẹ̀rù ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀,
òun ní i ṣe ìlàjà ní ibi gíga gíga ọ̀run.
3Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí,
tàbí ara ta ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí?
4Èéha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run?
Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́?
5Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀,
àní àwọn ìràwọ̀ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀,
6kí a má sọ ènìyàn tí i ṣe ìdin,
àti ọmọ ènìyàn tí í ṣe kòkòrò!”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jobu 25: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀