Nítorí náà ó tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ, ẹ̀yin yóò sì wá mi, ẹ ó sì kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá.” Nítorí náà àwọn Júù wí pé, “Òun ó ha pa ara rẹ̀ bí? Nítorí tí ó wí pé, ‘Ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ̀yin kì yóò lè wá’?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ìsàlẹ̀ wá; èmi ti òkè wá; ẹ̀yin jẹ́ ti ayé yìí; èmi kì í ṣe ti ayé yìí. Nítorí náà ni mo ṣe wí fún yín pé, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín: nítorí bí kò ṣe pé ẹ bá gbàgbọ́ pé èmi ni, ẹ ó kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín.” Nítorí náà wọ́n wí fún un pé, “Ta ni ìwọ jẹ́?” Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ni èyí tí mo ti wí fún yín ní àtètèkọ́ṣe. Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ, àti láti ṣe ìdájọ́ nípa yín: ṣùgbọ́n olóòtítọ́ ni ẹni tí ó rán mi, ohun tí èmi sì ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá, wọ̀nyí ni èmi ń sọ fún aráyé.” Kò yé wọn pé ti Baba ni ó ń sọ fún wọn. Lẹ́yìn náà Jesu wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ mọ̀ pé, nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ ènìyàn sókè, nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé èmi ni àti pé èmi kò dá ohunkóhun ṣe fún ara mi; ṣùgbọ́n bí Baba ti kọ́ mi, èmí ń sọ nǹkan wọ̀nyí. Ẹni tí ó rán mí sì ń bẹ pẹ̀lú mi: kò fi mí sílẹ̀ ní èmi nìkan; nítorí tí èmi ń ṣe ohun tí ó wù ú nígbà gbogbo.” Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà á gbọ́.
Kà Johanu 8
Feti si Johanu 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Johanu 8:21-30
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò