Jeremiah 8
8
1“ ‘Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, wọn yóò mú egungun àwọn ọba Juda àti egungun àwọn ìjòyè, egungun àwọn àlùfáà àti egungun àwọn wòlíì àti egungun àwọn olùgbé Jerusalẹmu kúrò nínú ibojì. 2A ó yọ wọ́n síta fún oòrùn àti òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tí wọ́n ti fẹ́ràn tí wọ́n sì ti sìn, àti àwọn tí wọ́n ti tọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì ti foríbalẹ̀ fún. Kì yóò ṣà wọ́n jọ tàbí sìn wọ́n, wọn yóò dàbí ìdọ̀tí tó wà lórí ilẹ̀. 3Níbikíbi tí mo bá lé wọn lọ, gbogbo àwọn ìyókù wọn yóò fẹ́ ikú ju ìyè lọ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.’
Ẹ̀ṣẹ̀ àti ìjìyà
4“Wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“ ‘Bí ènìyàn bá ṣubú lulẹ̀
wọn kì í padà dìde bí? Nígbà tí
ènìyàn bá yà kúrò ní ọ̀nà rẹ,
kì í yí padà bí?
5Èéṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyí
fi yà kúrò lọ́nà rẹ̀? Kí ló dé tí Jerusalẹmu
fi yà kúrò ní gbogbo ìgbà?
Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn, wọ́n kọ̀ láti yípadà.
6Mo ti fetísílẹ̀ dáradára, wọn
kò sọ ohun tí ó tọ́. Kò sí ẹnìkan tó
ronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀,
kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?” Olúkúlùkù
ń tọ ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun.
7Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbà
tirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé
mọ àkókò ìṣípò padà wọn. Ṣùgbọ́n àwọn
ènìyàn mi kò mọ ohun tí Ọlọ́run wọn fẹ́.
8“ ‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n,
nítorí a ní òfin Olúwa,” nígbà
tí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọn
akọ̀wé ti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn
9Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n, a ó dà
wọ́n láàmú, wọn yóò sì kó sí ìgbèkùn.
Nítorí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa. Irú ọgbọ́n
wo ló kù tí wọ́n ní?
10Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fún
àwọn ọkùnrin mìíràn àti ilẹ̀ wọn
fún àwọn ẹlòmíràn láti èyí tó kéré
jù dé èyí tó dàgbà jù, gbogbo wọn
ni èrè àjẹjù ń jẹ lógún; àwọn wòlíì
àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ń hùwà ẹ̀tàn.
11Wọ́n tọ́jú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́
bí èyí tí kò jinlẹ̀.
“Àlàáfíà, àlàáfíà,” ni wọ́n ń wí,
nígbà tí kò sí àlàáfíà.
12Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn? Bẹ́ẹ̀ kọ́,
wọn kò ní ìtìjú rárá; wọn kò tilẹ̀ mọ
bí wọ́n ti ṣe ń tì jú. Nítorí náà
wọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tó ti ṣubú,
a ó sì wó wọ́n lulẹ̀ nígbà tí a bá bẹ̀ wọ́n wò,
ni Olúwa wí.
13“ ‘Èmi yóò mú ìkórè wọn kúrò
ni Olúwa wí.
Kì yóò sí èso lórí igi àjàrà,
kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi, ewé wọn yóò sì rẹ̀ sílẹ̀.
Ohun tí mo ti fi fún wọn ni à ó gbà kúrò.’ ”
14“Èéṣe tí àwa fi jókòó ní ibí yìí?
A kó ara wa jọ!
Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi
kí a sì ṣègbé síbẹ̀.
Nítorí tí Olúwa Ọlọ́run wa ti pinnu pé a ó ṣègbé.
Yóò sì fún wa ní omi onímájèlé mu,
nítorí àwa ti ṣẹ̀ sí i.
15Àwa ń retí àlàáfíà,
kò sí ìre kan
tí ó wá ní ìgbà ìmúláradá
bí kò ṣe ìpayà nìkan.
16Ìró ìfọn imú ẹṣin àwọn ọlọ̀tẹ̀
là ń gbọ́ láti Dani,
yíyan àwọn akọ ẹṣin
mú gbogbo ilẹ̀ wárìrì.
Wọ́n wá láti pa ilẹ̀ náà run,
gbogbo ohun tó wà níbẹ̀,
ìlú náà àti gbogbo olùgbé ibẹ̀.”
17“Wò ó, èmi yóò rán àwọn ejò olóró sí àárín yín,
paramọ́lẹ̀ tí ẹ kò lè pa oró wọn,
yóò sì bù yín jẹ,”
ni Olúwa wí.
18Olùtùnú mi, nígbà tí ìbànújẹ́ ọkàn mi
rẹ̀wẹ̀sì nínú mi.
19Fetí sí ẹkún àwọn ènìyàn mi láti ilẹ̀ jíjìnnà wá:
“Olúwa kò ha sí ní Sioni bí?
Ọba rẹ̀ kò sí níbẹ̀ mọ́ ni?”
“Èéṣe tí wọ́n fi mú mi bínú pẹ̀lú ère wọn, pẹ̀lú àwọn
òrìṣà àjèjì tí wọn kò níláárí?”
20“Ìkórè ti rékọjá,
ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti parí
síbẹ̀ a kò gbà wá là.”
21Níwọ́n ìgbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run, èmi náà run pẹ̀lú,
èmi ṣọ̀fọ̀, ìrora sì mú mi káká.
22Kò ha sí ìkunra ní Gileadi bí?
Kò ha sí àwọn oníṣègùn níbẹ̀?
Kí ló ha dé tí kò fi sí ìwòsàn
fún ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi?
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jeremiah 8: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.