Jakọbu Ìfáárà

Ìfáárà
A kọ ìwé Jakọbu sí àwọn Kristiani Júù láti jẹ́ kí wọn rí ìlànà àti ẹ̀kọ́ inú ìgbé ayé Kristi. Àwọn ìṣòro tó sọ̀rọ̀ lè ṣe àfihàn àwọn nǹkan tó ń dá wàhálà sílẹ̀ nílé Ọlọ́run. A kà nípa ìgbéraga, ìyara-ẹni-sọ́tọ̀, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìwà àgàbàgebè, ìkóhun-ayé-léyà, àti ìṣọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn. Jakọbu kọ̀wé láti mú kí àtúnṣe kí ó wà lórí àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí nípa ìfihàn pé ìgbàgbọ́ láìsí iṣẹ́ òkú ni (2.26); ó ń sọ pé ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ nìkan kò tó. Ìgbàgbọ́ tòótọ́ yóò mú ìgbé ayé rere wá bí igi rere yóò ṣe mú èso rere jáde yàtọ̀ sí ẹ̀gún èṣùṣú.
Jakọbu tẹnumọ́ ọn bí gbígbé ìgbé ayé Kristi ṣe jẹ́ pàtàkì tó láti fihàn bí ìgbàgbọ́ ènìyàn ṣe gbọdọ̀ jẹ́ tọkàntọkàn àti láti jẹ́ kí gbogbo ayé mọ̀ pé ìhìnrere máa ń yí ìgbé ayé ènìyàn padà. Bí ẹnikẹ́ni bá sọ pé Kristi ni òun tí ń kò sì rí ìyàtọ̀ nínú ayé rẹ̀, kò sàn ju aláìgbàgbọ́ lọ. Ní òtítọ́, ìhìnrere ń yí ìgbé ayé padà bí a bá fi ara wa fún Kristi, a ó sì rí i dájú pé láti inú ayé ìgbàgbọ́ ni ìfẹ́ tí kì í kú àti ìbùkún yóò tì sàn wá.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Ìgbé ayé Kristiani òtítọ́ 1.1-27.
ii. Àwùjọ Kristiani 2.1-13.
iii. Ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ 2.14-26.
iv. Ọ̀rọ̀ lórí kíkó ahọ́n ní ìjánu 3.1-18.
v. Ọ̀rọ̀ ìyànjú 4.1-17.
vi. Ìkìlọ̀ fún àwọn ọlọ́rọ̀ 5.1-6.
vii. Ọ̀rọ̀ ìyànjú ìgbẹ̀yìn 5.7-20.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jakọbu Ìfáárà: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀