Jakọbu 5:13-20

Verse Image for Jakọbu 5:13-20

Jakọbu 5:13-20 - Inú ẹnikẹ́ni ha bàjẹ́ nínú yín bí? Jẹ́ kí ó gbàdúrà. Inú ẹnikẹ́ni ha dùn? Jẹ́ kí ó kọrin mímọ́. Ẹnikẹ́ni ha ṣe àìsàn nínú yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ìjọ, kí wọ́n sì gbàdúrà sórí rẹ̀, kí wọn fi òróró kùn ún ní orúkọ Olúwa: Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì gba aláìsàn náà là, Olúwa yóò sì gbé e dìde; bí ó bá sì ṣe pé ó ti dẹ́ṣẹ̀, a ó dáríjì í. Ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún ara yín, kí a lè mú yín láradá. Iṣẹ́ tí àdúrà olódodo ń ṣe ní agbára púpọ̀.
Ènìyàn bí àwa ni Elijah, ó gbàdúrà gidigidi pé kí òjò kí ó má ṣe rọ̀, òjò kò sì rọ̀ sórí ilẹ̀ fún ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà. Ó sì tún gbàdúrà, ọ̀run sì tún rọ̀jò, ilẹ̀ sì so èso rẹ̀ jáde.
Ará, bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣìnà kúrò nínú òtítọ́, tí ẹni kan sì yí i padà; Jẹ́ kí ó mọ̀ pé, ẹni tí ó bá yí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan padà kúrò nínú ìṣìnà rẹ̀, yóò gba ọkàn kan là kúrò lọ́wọ́ ikú, yóò sì bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.