Isaiah 66
66
Ìdájọ́ àti ìrètí
1 Báyìí ni Olúwa wí:
“Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,
ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi,
Níbo ni ilé tí ẹ ó kọ́ fún mi wà?
Níbo ní ibi ìsinmi mi yóò gbé wà?
2Kì í ha á ṣe ọwọ́ mi ló tí ṣe nǹkan wọ̀nyí,
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì wà?”
ni Olúwa wí.
“Eléyìí ni ẹni tí mo kà sí:
ẹni náà tí ó rẹra rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì kẹ́dùn ní ọkàn rẹ̀,
tí ó sì wárìrì sí ọ̀rọ̀ mi.
3Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fi akọ màlúù rú ẹbọ
ó dàbí ẹni tí ó pa ènìyàn kan
àti ẹni tí ó bá fi ọ̀dọ́-àgùntàn kan tọrẹ,
dàbí ẹni tí ó bẹ́ ajá kan lọ́rùn;
ẹnikẹ́ni tí ó bá fi irúgbìn ìyẹ̀fun tọrẹ
dàbí ẹni tí ó mú ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ wá,
ẹni tí ó bá sì sun tùràrí ìrántí,
dàbí ẹni tí ó súre fún òrìṣà.
Wọ́n ti yan ipa ọ̀nà tì wọ́n,
ọkàn wọn pẹ̀lú sì láyọ̀ nínú ohun ìríra wọn;
4Fún ìdí èyí ni èmi pẹ̀lú yóò ṣe fi ọwọ́ líle mú wọn
n ó sì mú ohun tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ wá sórí wọn.
Nítorí nígbà tí mo pè, kò sí ẹni tí ó dáhùn,
nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹnikẹ́ni kò tẹ́tí sílẹ̀.
Wọ́n ṣe ohun búburú ní ojú mi
wọ́n sì yan ohun tí mo kórìíra rẹ̀.”
5Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa,
Ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀:
“Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kórìíra yín,
tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé,
‘Jẹ́ kí a yin Olúwa lógo,
kí a le rí ayọ̀ yín!’
Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì.
6 Gbọ́ rògbòdìyàn láti ìlú wá,
gbọ́ ariwo náà láti tẹmpili wá!
Ariwo tí Olúwa ní í ṣe
tí ó ń san án fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ ohun
tí ó tọ́ sí wọn.
7 “Kí ó tó lọ sí ìrọbí,
ó ti bímọ;
kí ó tó di pé ìrora dé bá a,
ó ti bí ọmọkùnrin.
8Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?
Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?
Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀-èdè kan níjọ́ kan
tàbí kí orílẹ̀-èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan?
Síbẹ̀síbẹ̀ Sioni bẹ̀rẹ̀ rírọbí
bẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀.
9Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọbí
kí èmi má sì mú ni bí?”
ni Olúwa wí.
“Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ
nígbà tí mo ń mú ìbí wá?”
Ni Ọlọ́run yín wí.
10“Ẹ bá Jerusalẹmu yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i,
gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀;
ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀,
gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un.
11Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùn
nínú ọmú rẹ̀ tí ó tu ni lára;
Ẹ̀yin yóò mu àmuyó
ẹ ó sì gbádùn nínú àkúnwọ́sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”
12Nítorí báyìí ni Olúwa wí:
“Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odò
àti ọrọ̀ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi;
ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀
a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀.
13Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú,
bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínú
a ó sì tù yín nínú lórí Jerusalẹmu.”
14Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú yín yóò dùn
ẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko;
ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mí mọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,
ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.
15Kíyèsi i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú iná
àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle;
òun yóò mú ìbínú rẹ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú,
àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná.
16Nítorí pẹ̀lú iná àti idà
ni Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ lórí i gbogbo ènìyàn,
àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí Olúwa yóò pa.
17“Gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì sọ ara wọn di mímọ́ láti lọ sínú ọgbà, tí wọ́n tẹ̀lé ẹni tí ó wà láàrín àwọn tí ó jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èkúté àti àwọn ohun ìríra mìíràn ni wọn yóò bá òpin wọn pàdé papọ̀,” ni Olúwa wí.
18“Àti Èmi, nítorí ìgbésẹ̀ wọn àti èrò wọn, èmi ti múra tán láti wá kó àwọn orílẹ̀-èdè àti ahọ́n jọ, wọn yóò sì wá wo ògo mi.
19“Èmi yóò sì gbé ààmì kan kalẹ̀ láàrín wọn, èmi yóò sì rán díẹ̀ nínú àwọn tí ó sálà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè Tarṣiṣi, sí àwọn ará Libia àti Ludi, sí Tubali àti ará Giriki, àti sí àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré tí kò tí ìgbọ́ nípa òkìkí mi tàbí kí ó rí ògo mi. Wọn yóò kéde ògo mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè. 20Wọn yóò sì mú àwọn arákùnrin yín wá, láti gbogbo orílẹ̀-èdè, sí òkè mímọ́ mi ní Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti ọkọ-ẹṣin, àti lórí ìbáaka àti ìbákasẹ,” ni Olúwa wí. “Wọn yóò kó wọn wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti mú ọrẹ oníhóró wọn wá, sínú Tẹmpili Olúwa nínú ohun èlò mímọ́. 21Àti pé èmi yóò sì yan àwọn kan nínú wọn pẹ̀lú láti jẹ́ àlùfáà àti Lefi,” ni Olúwa wí.
22 “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun tí mo dá yóò ṣe wà níwájú mi títí láé,” ni Olúwa wí, “Bẹ́ẹ̀ ni orúkọ yín àti ìrandíran yín yóò pegedé. 23Láti oṣù tuntun kan dé òmíràn àti láti ọjọ́ ìsinmi kan dé òmíràn, ni gbogbo ọmọ ènìyàn yóò wá, wọn yóò sì tẹríba níwájú mi,” ni Olúwa wí. 24 “Wọn yóò sì jáde lọ wọn yóò sì lọ wo òkú àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ sí mi; kòkòrò wọn kì yóò kú, bẹ́ẹ̀ ni iná wọn ni a kì yóò pa, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jẹ́ ohun ìríra fún gbogbo ọmọ ènìyàn.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isaiah 66: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.