Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn orin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀; Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú. Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà sí i. Ó kọ́ ilé ìṣọ́ sí inú rẹ̀ ó sì ṣe ìfúntí kan síbẹ̀ pẹ̀lú. Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára, ṣùgbọ́n èso búburú ni ó ti ibẹ̀ wá. “Ní ìsinsin yìí ẹ̀yin olùgbé Jerusalẹmu àti ẹ̀yin ènìyàn Juda ẹ ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti ọgbà àjàrà mi. Kín ni ó kù tí n ò bá túnṣe sí ọgbà àjàrà mi. Ju èyí tí mo ti ṣe lọ? Nígbà tí mo ń wá èso dáradára, èéṣe tí ó fi so kíkan? Ní ìsinsin yìí, èmi yóò wí fún ọ ohun tí n ó ṣe sí ọgbà àjàrà mi: Èmi yóò gé igi inú rẹ̀ kúrò, a ó sì pa á run, Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀ yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀. Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro láì kọ ọ́ láì ro ó, ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀. Èmi yóò sì pàṣẹ fún kurukuru láti má ṣe rọ̀jò sórí i rẹ̀.” Ọgbà àjàrà OLúWA àwọn ọmọ-ogun ni ilé Israẹli àwọn ọkùnrin Juda sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀. Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí, Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke.
Kà Isaiah 5
Feti si Isaiah 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isaiah 5:1-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò