NISISIYI, emi o kọ orin si olufẹ ọwọ́n mi, orin olùfẹ mi ọwọ́n niti ọ̀gba àjara rẹ̀. Olufẹ ọwọ́n mi ni ọ̀gba àjara lori okè ẹlẹtù loju:
O si sọ ọ̀gba yi i ka, o si ṣà okuta kuro ninu rẹ̀, o si gbìn ayànfẹ àjara si inu rẹ̀, o si kọ ile iṣọ sãrin rẹ̀, o si ṣe ifunti sinu rẹ̀ pẹlu: o si wò pe ki o so eso, ṣugbọn eso kikan li o so.
Njẹ nisisiyi, ẹnyin ara Jerusalemu ati ẹnyin ọkunrin Juda, emi bẹ̀ nyin, ṣe idajọ lãrin mi, ati lãrin ọ̀gba àjara mi.
Kini a ba ṣe si ọ̀gba àjara mi ti emi kò ti ṣe ninu rẹ̀, nigbati mo wò pe iba so eso, ẽṣe ti o fi so eso kikan?
Njẹ nisisiyi, ẹ wá na, emi o sọ ohun ti emi o ṣe si ọ̀gba àjara mi fun nyin: emi o mu ọ̀gba rẹ̀ kuro, a o si jẹ ẹ run, emi o wo ogiri rẹ̀ lu ilẹ, a o si tẹ̀ ẹ mọlẹ.
Emi o si sọ ọ di ahoro, a kì yio tọ́ ẹka rẹ̀, bẹ̃ni a kì yio wà a, ṣugbọn ẹ̀wọn ati ẹ̀gún ni yio ma hù nibẹ, emi o si paṣẹ fun awọsanma ki o má rọjò sori rẹ̀.
Nitori ọ̀gba àjara Oluwa awọn ọmọ-ogun ni ile Israeli, ati awọn ọkunrin Juda ni igi-gbìgbin ti o wù u, o reti idajọ, ṣugbọn kiyesi i, inilara; o si reti ododo; ṣugbọn kiyesi i, igbe.