Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí OLúWA wí nìyìí
ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu
ẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Israẹli:
“Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;
Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe.
Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,
Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ;
àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá
wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.
Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,
kò ní jó ọ;
ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.
Nítorí Èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ,
Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ;
Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ,
Kuṣi àti Seba dípò rẹ.
Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi,
àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ,
Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ,
àti ènìyàn dípò ẹ̀mí rẹ.
Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;
Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà-oòrùn wá
èmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀-oòrùn.
Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’
Àti fún gúúsù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’
Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jíjìn wá
àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—
ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́,
tí mo dá fún ògo mi,
tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”
Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde,
tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití.
Gbogbo orílẹ̀-èdè kó ra wọn jọ
àwọn ènìyàn sì kó ra wọn papọ̀.
Ta ni nínú wọn tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí
tí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀?
Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wá
láti fihàn pé wọ́n tọ̀nà
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́, tí
wọn yóò sọ pé, “Òtítọ́ ni.”
“Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni OLúWA wí,
“Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn,
tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà mí gbọ́
tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà.
Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá,
tàbí a ó wa rí òmíràn lẹ́yìn mi.
Èmi, àní Èmi, Èmi ni OLúWA,
yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn.
Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kéde
Èmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrín yín.
Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni OLúWA wí, “Pé Èmi ni Ọlọ́run.
Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà.
Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi.
Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”