“Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́? Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìròyìn in rẹ̀ fún? Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú wọn, sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú. Nítorí tí í ṣe: báyìí ni orí Ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe, àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn.” Ó dára báyìí, pẹ̀lú ètè àjèjì àti ahọ́n àìmọ̀ Ọlọ́run yóò bá àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀ àwọn tí ó sọ fún wí pé, “Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”; àti pé, “èyí ni ibi ìsinmi” ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sílẹ̀. Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ OLúWA sí wọn yóò di pé Ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe, àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubú sẹ́yìn, wọn yóò fi ara pa, wọn yóò bọ́ sínú okùn a ó sì gbá wọn mú.
Kà Isaiah 28
Feti si Isaiah 28
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Isaiah 28:9-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò