Isaiah 25:6-9

Isaiah 25:6-9 YCB

Ní orí òkè yìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun yóò ti pèsè àsè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyàn àpèjẹ ti ọtí wáìnì àtijọ́ ti ẹran tí ó dára jù àti ti ọtí wáìnì tí ó gbámúṣé. Ní orí òkè yìí ni yóò pa aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn, abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀; Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé. OLúWA Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù, kúrò ní ojú gbogbo wọn; Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé. OLúWA ni ó ti sọ ọ́. Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé, “Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa; àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là. Èyí ni OLúWA, àwa gbẹ́kẹ̀lé e, ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”