Hosea Ìfáàrà
Ìfáàrà
Ìwé yìí, ṣàlàyé ìgbé ayé ìdílé Hosea gẹ́gẹ́ bí ààmì láti fi ẹsẹ̀ ọ̀rọ̀ tí wòlíì gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa sí àwọn ènìyàn rẹ̀ múlẹ̀. Nínú un rẹ̀ ni Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Hosea láti fẹ́ àgbèrè obìnrin ní ìyàwó èyí tí í ṣe Gomeri, tí ó sì bí ọmọ mẹ́ta, èyí tí ó fún wọn ní àwọn ààmì orúkọ tí ó fiwé àwọn Israẹli tí wọ́n kọ Ọlọ́run sílẹ̀, ṣùgbọ́n tí Ọlọ́run kò wo ti àìṣedéédéé wọn, tí ó sì mú wọn padà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Èyí fi bí Olúwa ṣe ni Ìfẹ́ májẹ̀mú àwọn ènìyàn rẹ̀ hàn ní Israẹli tí ó sì mú wọn padà, bí Hosea ṣe gba Gomeri padà.
Hosea pe ìpè fún ìrònúpìwàdà. Ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli kí wọ́n fi òrìṣà wọn sílẹ̀ kí wọn sì padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa. Hosea rí ìkùnà sí àwárí ìmọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀ wàhálà Israẹli. Ó tún jẹ́ kí ó yé wa pé ì bà ṣe pọ̀ Ọlọ́run sí àwọn ọmọ Israẹli ní Ìfẹ́. Èyí ló jẹ́ kí á mọ̀ ì bà ṣe pọ̀ tó wà láàrín ọkọ àti Ìyàwó àti láàrín baba àti ọmọ. Ohun tí ó tún fi yé ni ni bí àwọn ọmọ Israẹli ṣe yípadà kúrò lọ́dọ́ Ọlọ́run tí wọ́n ń sin òrìṣà, tí wọ́n gbẹ́ ère fún ara wọn tí wọ́n sì ń ṣe àgbèrè. Ohun tí ó ṣe pàtàkì jù nínú ìwé yìí ni àánú àti ìfẹ́ Ọlọ́run tí kò jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ ṣègbé.
Kókó-ọ̀rọ̀
i. Aláìlóòótọ́ Ìyàwó àti ọkọ olóòtítọ́ 1.1–3.5.
ii. Àìní òtítọ́ Israẹli 4.1–6.3.
iii. Ìjìyà Israẹli 6.4–10.15.
iv. Òtítọ́ ìfẹ́ Olúwa 11–14.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Hosea Ìfáàrà: YCB
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc.
A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé.
Yoruba Contemporary Bible
Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.®
Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.