Hosea 12

12
1Efraimu ń jẹ afẹ́fẹ́;
o ń lépa afẹ́fẹ́ ìwọ̀-oòrùn ní gbogbo ọjọ́.
O sì ń gbèrú nínú irọ́
o dá májẹ̀mú pẹ̀lú Asiria
o sì fi òróró olifi ránṣẹ́ sí Ejibiti.
2 Olúwa ní ẹjọ́ kan tí yóò bá Juda rò,
yóò fì ìyà jẹ Jakọbu gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀
yóò sì sán fún un gẹ́gẹ́ bí i ìṣe rẹ̀.
3Láti inú oyún ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀,
àti nípa ipá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run
4Ó bá angẹli ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀
o sọkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojúrere rẹ̀
Ó bá Olúwa ní Beteli
Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀,
5àní Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun;
Olúwa ni orúkọ ìrántí rẹ̀
6Ṣùgbọ́n ìwọ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀;
di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mú
kí ẹ sì dúró de Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.
7Oníṣòwò ń lo òṣùwọ̀n èké
o fẹ́ràn láti rẹ́ ni jẹ.
8 Efraimu gbéraga,
“Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀,
pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé
tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́.”
9“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ;
ẹni tí ó mu ọ jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti;
èmi yóò tún mú yín gbé nínú àgọ́
bí i ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn wọ̀n-ọn-nì
10Mo sọ fún àwọn wòlíì,
mo fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran hàn wọ́n
mo sì pa òwe láti ẹnu wòlíì wọn.”
11Gileadi ha burú bí?
Àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ asán.
Ǹjẹ́ wọ́n ń fi akọ màlúù rú ẹbọ ní Gilgali?
Gbogbo pẹpẹ wọ́n sì dàbí ebè
nínú aporo oko.
12Jakọbu sálọ si orílẹ̀-èdè Aramu;
Israẹli sìn kí o tó fẹ́ ìyàwó
ó ṣe ìtọ́jú ẹran láti fi san owó ìyàwó.
13 Olúwa lo wòlíì kan láti mú Israẹli jáde wá láti Ejibiti,
nípasẹ̀ wòlíì kan ó ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
14Ṣùgbọ́n Efraimu ti mú un bínú gidigidi;
Olúwa rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀bi ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sí orí rẹ̀
òun yóò sì san án padà fún un nítorí ìwà ẹ̀gàn an rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Hosea 12: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀